Ọkùnrin tó bá obìnrin ẹni àádọ́ta ọdún lòpọ̀ títí tó fi kú dèrò àtìmọ́lé l’Ondo

Court

Oríṣun àwòrán, Arek Socha/Pixabay

Ile ẹjọ majistreeti kan niluu Akure ti sọ ọkunrin kan, James Emmanuel, si atimọle ọgba ẹwọn lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ba iyawo ile kan, Deborah Abiodun, lopọ titi to fi jade laye.

Afurasi naa dero agọ ọlọpaa lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii lẹyin iku obinrin naa to jẹ alabaṣiṣẹ rẹ.

Iroyin ni lẹyin ti James fi ipa ba obinrin naa lopọ tan lo fọ okuta mọ ori rẹ, to si ju oku rẹ sinu koto kan.

Lẹyin ti akara Jemes tu sepo tan ni wọn gbe lọ sile ẹjọ lori ẹsun meji ọtọtọ to rọ mọ ifipabanilopọ ati ipaniyan.

Agbẹjọro ijọba, Anwana Josephine, sọ fun ile ẹjọ pe nnkan bii aago mọkanla alẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye, eyii to lodi si abala ofin 357 ti ijiya rẹ wa ni abala ofin 357 ti wọn gbe kalẹ nipinlẹ Ondo lọdun 2006.

Iwe ipẹjọ afurasi naa ni “Pe iwọ James Emmanuel, ọkunrin, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni nnkan bii aagọ mọkanla alẹ, ni Ilere, loju ọna ilu Ijare.

“Fi ipa ba Deborah Abiodun, to jẹ obinrin, ẹni ọdun marunlelaadọta lopọ.

“Nitori naa o ti ṣẹ labẹ ofin 357 ti ijiya rẹ wa ni abala ofin 357 ti wọn gbe kalẹ nipinlẹ Ondo lọdun 2006.

“Ati pe iwọ James Emmanuel lọjọ kan naa tun ṣ ekupa Deborah Abiodun nipa lila okuta mọ oloogbe naalori, ti o si ju oku rẹ sinu koto nibi ti wọn n da idọti si, eyii to lodi si ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ondo ni abala 316, ti ijiya rẹ wa ni abala 319 (1) ti wọn gbe kalẹ lọdun 2006.”

Adajọ F.A. Aduroja ni ki afurasi ọhun ṣi lọ maa gba atẹgun ni ọgba ẹwọn to wa niluu Ondo titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii ti igbẹjọ ọhun yoo tẹsiwaju.