“Gbogbo nǹkan ló le koko ní Argentina, a kò lè jẹ ẹran màálù mọ́”

- Author, James Menendez and Alba Morgade
- Role, STAFF
- Reporting from, BBC World Service, Buenos Aires
Lakoko igba kan, Argentina wa lara orilẹ-ede to lọla julọ lagbaye, koda, o lola ju France ati Germany lọ.
Pupọ lara ọrọ rẹ lo n ri lara ẹran maalu to n ta si ilẹ okeere ni nnkan bii ọgọrun run ọdun sẹyin.
Amọ lọwọ yii, orilẹ-ede naa ti dero ẹyin laarin awọn ilẹ ọlọlaa lagbaye, koda ipo aadọrin lo wa lara awọn orilẹ-ede ọlọla gẹgẹ bii atẹjade banki agbaye.
Ni bayii, bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede naa ṣi ni ọpọ maalu, ogunlọgọ awọn eeyan ile ọhun ni ko to ẹni to n jẹ ẹran maalu mọ, lara wọn ni Oriana ati Samir, ti wọn jẹ tọkọtaya to n gbe niluu Buenos Aires.
Oriana ni “Ko rọrun rara, gbogbo igba ni a maa bere lọwọ ara wa pe bawo ni a ṣe maa ri ounjẹ oojọ jẹ.
“A n gbe nilẹ to ni ọpọ maalu amọ ẹran adiyẹ ni a n jẹ nitori owo rẹ ko wọn to owo ẹran maalu.”
Awọn ti ko rọwọ họri gan ko ri ẹran adiyen naa jẹ ayafi awọn to lowo lọwọ.
Tọkọtaya ọhun ti wọn ni ọmọ obinrin kekere kan ti orukọ rẹ n jẹ Chiara sọ pe ko rọrun lati bọ ara wọn.
Yatọ si iṣoro ounjẹ oojọ, eto abo tun mẹhẹ nibẹ.
Samir, to jẹ awakọ akẹru ni “Eto abo ko ṣe dede, awọn ọmọ ita le pa eeyan nitori ẹrọ ilewọ rẹ lasan laarin adugbo.”
Iwadii fi han pe ida 40% eeyan awọn orilẹ-ede naa lo n gbe ninu iṣẹ ati oṣi, ẹnu ọjọ mẹta yii si ni wọn dibo fun Aarẹ tuntun, Javier Milei, eyii ti wọn gbagbọ pe yoo tun ipin ilẹ naa ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Claudio Paez, to jẹ oniṣowo to ni ṣọọbu mejila ni ojojumọ ni gbogbo nnkan n le si bii oju ẹja.
Ṣọọbu rẹ mejila to ti n ta nnkan jijẹ ti ku meji pere bayii.
O ni “Ti nnkan ba tẹtiwasju bo ṣe n lọ yii, laarin oṣu diẹ si asiko yii, mi o ni le maa bọ ara mi mọ.”
Ojojumọ ni nkan n le si ni Argentina, ti ọpọ araalu si n pariwo ebi.
Iye owo ti Argentina n na pọ ju iye owo to n pa wọle lọ.
Lọwọ yii, iye gbese to jẹ ajọ adojutofo agbaye, International Monetary Fund, ti le ni $44bn, eyii to mu ko jẹ orilẹ-ede ti gbese rẹ pọ julọ lọdọ IMF ni gbogbo agbaye.

Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Milei ti sọ pe oun ni idahun si gbogbo ibere awọn eeyan ilẹ naa, oun si le tan iṣoro ti ọrọ aje wọn n dojukọ.
Oniruru ileri lo ṣe fun awọn eeyan naa lasiko ipolongo ibo Aarẹ.
Lara ileri naa ni pe oun yoo ko owo ilẹ naa, Peso, kuro nilẹ, ti orilẹ-ede ọhun yoo si maa na owo dọla ilẹ Amẹrika.

Ni bayii, Milei ti mu adinku ba iye awọn eeyan to n ṣejọba lọna ati din iye owo ti ijọba yoo maa na ku.
Onimọ nipa oun to n lọ kan, Sergio Berensztein, sọ pe ohun to dara ni Milei n ṣe, yoo si fọ ilẹ naa mọ lọwọ iṣẹ ati oṣi laipẹ.












