Ààrẹ yọ adájọ́ àgbà nípò lórí ẹ̀sùn àṣìlò ipò tí àráàlú kan fi kàn án

Oríṣun àwòrán, Ghana Presidency
Aarẹ John Mahama ti yọ adajọ agba orilẹede naa, Gertrude Torkornoo, nipo.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin imọran igbimọ kan to ṣewadi ẹsun ti ọmọbibi Ghana kan, Daniel Ofori, fi kan adajọ agba naa.
Ileeṣẹ aarẹ Ghana ni igbimọ oluwadii ẹlẹni marun un fi idi rẹ mulẹ pe Torkornoo ṣiwa hu pẹlu ọọfiisi rẹ, idi si niyii ti aarẹ fi rọ ọ loye.
Yiyọ adajọ agba nipo ko tii ṣẹlẹ ri lati ọdun 1992 ti orilẹede Ghana ti pada si ijọba awarawa.
Nigba ti ijọba n sọ pe igbesẹ naa tọna labẹ ofin, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako kan ti sọ pe igbesẹ to kudiẹ kaato ni, o si lewu fun ominira ẹka eto idajọ.
Igbimọ ẹlẹni marun un to ṣe iwadii ẹsun ti Ofori fi kan Arabinrin Torkornoo ṣalaye pe awọn gbọ atotonu ati awijare awọn mejeeji tọrọ kan kawọn to gba aarẹ ni imọran lati yọ agbẹjọro agba naa nipo.
Ileeṣẹ aarẹ ṣalaye pe igbimọ to ṣewadii Arabinrin Torkornoo ṣe agbeyẹwo ẹri to wa loju ewe iwe 10,000 lori ọrọ adajọ agba naa.
Ileeṣẹ aarẹ Ghana tun sọ pe igbimọ naa tun gbọ lati ẹnu ẹlẹrii Ọgbẹni Ofori mẹtala ati ẹlẹrii mejila mii to fi mọ awọn akọṣẹmọṣẹ ninu ofin ti Arabinrin Torkornoo fun ra rẹ mu wa.
Ẹgbẹ oṣelu alatako ni yiyọ adajọ agba nipo lọwọ oṣelu ninu

Oríṣun àwòrán, Ghana Presidency
Lati oṣu Kẹrin ọdun yii ni Aarẹ Mahama ti ni ki adajọ agba naa lọ rọkun nle, nigba to ṣe agbeyẹwo ẹsun tawọn eeyan mẹta to n pe fun iyọnipo rẹ fi kan an.
Ṣaaju ni ẹgbẹ New Patriotics Party to jẹ ẹgbẹ oṣelu alatako ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu bi Aarẹ Mahama ṣe jawee gbele ẹ fun Torkornoo loṣu Kẹrin ọdun yii.
Ẹgbẹ naa ni igbesẹ aarẹ lọwọ oṣelu ninu, ati pe o lewu fun ominira ẹka eto idajọ.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Torkornoo ni wi pe o fi igba kan bọ ikan ninu lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ bayii ti wọn jẹ ẹgbẹ alatako tẹlẹ.
Amọ, Arabinrin Torkornoo loun o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ọpọ igba lawọn eeyan ti pe adajọ agba naa lẹjọ sẹyin lati yọ ọ nipo, amọ, pabo ni gbogbo rẹ jasi nigba naa.
Ọrọ adajọ agba Torkornoo ti Aarẹ Ghana tẹlẹ, Nana Akufo-Addo, yan sipo lọdun 2023 ti n fa awuyewuye lori ayelujara.















