Iléeṣẹ́ ọlọ́páà Eko fi òfin de bí àwọn egúngún ṣe má n jó kiri ìgboro

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe o ti di eewọ fun awọn egungun lati maa ko ara wọn kaakiri igboro ipinlẹ naa lasiko ọdun to n lọ lọwọ, ayafi awọn agbegbe ti ọdun ọhun ba ti n waye nikan.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ naa, CSP Benjamin Hundeyin sọ pe aṣẹ naa waye lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu ti yoo si maa fi asiko kan naa bọwọ fun ẹsin awọn araalu mii.
Hundeyin sọ pe "Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fẹ fi akoko yii kede pe awọn Egungun ko gbọdọ kọja awọn agbegbe ti ọdun wọn yoo ti waye nikan.
"Aṣẹ yii tumọ si pe awọn to ti yoo ṣe odun ko gbọdọ maa ko ara wọn kaakiri adugbo lọna ati ri daju pe abo wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu.
"Ati lati ri daju pe awọn to n ṣe ọdun Egungun bọwọ fun ẹtọ awọn araalu ti wọn ni ẹsin mii lasiko ọdun Egungun to n lọwọ."
Ileeṣẹ ọlọpaa ni aṣẹ yii waye lẹyin ti oniruru awọn iroyin tẹ awọn lọwọ lori bi rogbodiyan ṣe maa n waye ati bi ija ṣe maa n ṣẹlẹ laarin awọn to n ṣe ọdun Egungun atawọn araalu mii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Hundeyin tẹsiwaju pe "Lati ri pe alaafia wa laarin ilu ati lati dena ija to maa n waye laarin awọn to n ṣe ọdun Egungun atawọn araalu mii, ati lati dena bi wọn ṣe n ba dukia awọn eeyan jẹ laarin ọjọ diẹ sẹyin, a rọ awọn to n ṣe ọdun Egungun ki wọn tẹle aṣẹ yii.
"Awọn eeyan aa tun gbọdọ kọ iwe si ọọfisi kọmiṣọna ọlọpaa lati bere fun abo ki Egungun atawọn ẹmẹwa rẹ to jade sita."
Lẹyin naa lo sọ pe ija to tọ labẹ ofin ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o tapa si ofin yii yoo jẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ọhun pari ọrọ rẹ pe "Ileeṣẹ ọlọpaa ko ni ṣai ma fi iya iya to tọ jẹ eyikeyi Egungun tabi awọn ẹmẹwaa rẹ ti a ba ri pe o tapa si ofin tabi tẹ ẹtọ araalu to jẹ ẹlẹsin mii mọlẹ nipinlẹ Eko."
Ṣaaju akoko yii ni awọn eleegun ti maa n ko ara wọn kaakiri igboro ti won a si maa fi agidi gba owo lọwọ awọn eeyan tabi na awọn ẹlomiran.
Lọpọ igba ni eyii maa n da ija silẹ laarin awọn eleegun naa atawọn ẹlẹsin mii.
Amọ ṣa, kii ṣe gbogbo awọn eleegun lo maa n dunkoko mọ araalu ni gbogbo igba.















