Àrùn Ebola tún ṣẹ́yọ, pa èèyàn 15 ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, OTHERS
O kere tan, eeyan mẹẹẹdogun lo ti jade laye bayii lorilẹede Olominira Congo, latari arun Ebola tuntun to ṣẹyọ nibẹ.
Ileeṣẹ eto ilera orilẹede Congo lo fidi eyi mulẹ.
Obinrin alaboyun ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan ni wọn kọkọ fidi rẹ mulẹ pe Ebola tuntun naa kọlu loṣu Kẹjọ, ti wọn si da a duro sile iwosan fun itọju.
Awọn apẹẹrẹ Ebola bii akọ iba, ki ẹjẹ maa jade kaakiri ara ati ki eeyan maa bi lai dawọ duro ni alaboyun naa fi han, ti wọn fi fura pe Ebola lo kọlu u.
Ileeṣẹ ilera orilẹede DR Congo fi kun un pe alaboyun yii pada ku lẹyin ọjọ diẹ, nigba ti awọn ẹya ara rẹ pupọ ti daṣẹ silẹ, ti wọn ko wulo fun un mọ.
Ninu eeyan mẹẹẹdogun ti wọn lo ti ku latari Ebola, mẹrin ninu wọn lo jẹ oṣiṣẹ eleto ilera bi wọn ṣe sọ.
Eyi ni igba kẹrindinlogun (16) ti Ebola yoo ṣẹyọ lorilẹede naa, latari ai si eto ilera kikun, ati idaamu ikọlu to n figba gbogbo koju wọn.
Awọn alaṣẹ ibẹ sọ pe eyi to ṣẹṣẹ gbode yii ṣẹyọ ni Aarin-gbungbun agbegbe Kasai, ati pe eeyan mejidinlọgbọn (28) ni akọsilẹ wa pe wọn ti lugbadi arun Ebola.
"Ẹ máa fọ ọwọ́ yín déédé''
Lati ṣẹgun Ebola to tun ṣẹyọ ọhun, awọn alaṣẹ orilẹede Congo ti gba awọn eeyan wọn nimọran lati ri I daju pe wọn n fọ ọwọ wọn deede.
Yatọ si eyi, wọn ni ki wọn ṣọra fun ikojọpọ ọpọ eeyan loju kan ṣoṣo, paapaa lawọn agbegbe ti o ti ṣee ṣe ki wọn fi ara kaasa arun naa ju.
Ayẹwo ti fi han pe irufẹ Ebola ti wọn n pe ni Zaire strain,lo ṣẹyọ yii. Ko wọpọ, ṣugbọn o lewu gidi bi wọn ṣe sọ.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilera lagbaaye (World Health Organisation), sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ yii kan, iyẹn awọn ibi ti apẹẹrẹ akọ iba ti n foju han lara alaisan, ti wọn n bi, ti wọn si n ṣegbọnsẹ gbuuru.
Ajọ naa kilọ pe o ṣee ṣe ki onka awọn ti Ebola kọlu pọ si i bi wọn ba n ko o ran ara wọn.
WHO ṣalaye pe awọn ti ran ikọ alabojuto pajawiri lọ si awọn ibi ti arun yii ti n ṣọṣẹ, ki wọn le fimu finlẹ mọ ibi to de duro, itọju to yẹ ati idena rẹ .
Wọn tun n pin awọn nnkan eelo aabo pẹlu bi wọn ṣe wi, eyi ti wọn le maa gbe rin kiri lati tete kapa arun naa nibikibi to ba ti ṣẹyọ.
Adari ẹkun ajọ WHO, Dokita Mohamed Janabi, ṣalaye pe awọn n ṣiṣẹ naa pẹlu ipinnu lati dẹkun Ebola yii kia.
O ni itọju ọlọkan-o-jọkan lo wa nilẹ lati ọdun 2000, eyi ti wọn fi kapa oriṣi Ebola ti a mọ si Ervebo Ebola.
O ni eyi naa lagbara lati dena Ebola tuntun to ṣẹyọ yii.
O ṣee ṣe ki wọn ko oogun itọju lati Kasai lọ si Kinshasa, lati fun awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni abẹrẹ ajẹsara to le dena kiko aisan naa.
Ọdun kẹta sẹyin ni Ebola ṣẹyọ ni DR Congo, eeyan mẹfa lo si pa.
Eyi to ṣẹyọ nibẹ ni 2018-20 lo le ju, eeyan to le ni ẹgbẹrun meji lo ba a lọ.
Ọdun 1976 ni kokoro Ebola kọkọ jade saye, eyi ti igbagbọ wa pe lara adan lo ti ṣẹyọ leti odo Ebola,nibi ti wọn n pe ni DR Congo bayii.
Bi eeyan ba ni ifarakora pẹlu ẹni to ni Ebola, yoo ran eeyan, tabi bi eeyan ba fi ẹnu ko wọn lẹnu, imu tabi fọwọ kan ẹjẹ, itọ tabi igbọnsẹ wọn.
Kí ló dé ti Ebola máa ń padà wá
Ebola maa n tete ràn.
Àágùn kekere tabi itọ lati ara eeyan tabi ẹranko to ba ni I lara le jẹ ki awọn eeyan miran ti ko ni I tẹlẹ naa lugbadi rẹ.
Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe wi, Ebola yoo maa ṣẹyọ titi ni DR Congo, nitori kokoro naa n gbe lara awọn ẹranko nibudo ti wọn ko wọn si kaakiri orilẹede naa.
Ẹranko ti a mọ si adan ni wọn lo ni kokoro Ebola lara ju, eeyan le ko o lara rẹ.
Ṣugbọn eeyan tun le ko o lara awọn ẹranko bii inaki, ọbọ, ijimere ati òòrẹ̀ (porcupines), bi ẹjẹ, ìtọ̀ tabi itọ́ wọn ba kan eeyan lara.
Arun yii pọ ni Congo, nitori awọn ẹranko yii naa wa nibẹ, ko si ṣee ṣe lati pa gbogbo awọn ẹranko naa tan.
Niwọn igba ti awọn eeyan ba ṣi n fi ọwọ kan wọn, ti wọn si n jẹ wọn, o ṣee ṣe ki Ebola ṣi maa pada wa.














