Ìyá tí wọ́n pa ọmọ rẹ̀ torí obìnrin l'Ekiti ń bèèrè ìdájọ́ òdodo

Iku ọmọ ko ṣeé dákẹ́ sí fun òbí, agaga nigba ti iku òhun ba ruju, to jọ dida ẹmi ẹni legbodo.
Eyi lo fa a ti iya kan, Ọmọbabinrin Adenike Adejugbe, ẹni ti ọmọ rẹ, Chukwuemeka Odims, pade iku òjìji nipinlẹ Ekiti ṣe n ke gbàjarè, to sì n kigbe idajo ododo.
Ninu alaye ti Iya Oloogbe se fun BBC News Yorùbá lo ti ni ọjọ buruku ni ọjọ Isegun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2025 jẹ fun idile oun.
O ni ọjọ naa ni Chukwuemeka kuro nile laaye, ti wọn si pe oun lati waa wo oku rẹ lọ́jọ́ keji.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Ọmọbabinrin Adenike Adejugbe ṣalaye nílé rẹ to wa ni lagbegbe Copers' Lodge, opopona New Iyin Road, Ado Ekiti, pe enikan tó n jẹ Abdullahi Saidi, lọwọ ninu iku àkọ́bí oun yii.
O ni:
"Awọn kan pe ọmọ mi lori ẹrọ ibanisọrọ lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, o gbe ounjẹ to fẹẹ jẹ silẹ, o si sare jade, sugbọn ko pada wale lọjọ naa mọ.
"Owurọ ọjọ keji ni mo ṣadeede ri awọn ọlọpaa nile mi, won ni ki n tele awọn de agọ awọn.
" Nibẹ lẹru ti ba mi, nitori ẹrọ ibanisọrọ ọmọ mi ti mo ti n pe tẹ́lẹ̀ n dun sugbọn ko gbe e, bakan naa ni mo tun ri awọn ara adugbo wa kọọkan nígbà ti a de agọ ọlọpaa, wọn n sọ pe awọn kan ja, awọn kan si wa nile iwosan."
Iya naa sọ pe abajade rẹ ni bi wọn ṣe ni ọmọ oun ti ku.
Nípa bi ọ̀rọ̀ ṣe ja siku ati pe ṣe obìnrin ni wọ́n torí e pa Chukwuemeka loootọ, iya rẹ ṣalaye pe oun ko mọ ọrẹbinrin kankan pẹlu Chukwuemeka rara.
O ni iṣẹ́ orin kíkọ ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn naa n ṣe nigba aye rẹ, oun ko mọ ti obìnrin nípa rẹ.
'' Ọ̀rẹ́ ni Oloogbe àtàwọn tó pa á ''

Obinna Collins, ọkan lara awọn aburo oloogbe to ba wa sọrọ lori iku naa, ṣàlàyé pe ọrẹ ni Chukwuemeka jẹ si awọn to ṣeku pa a.
"Wọn jọ n ṣe wọle-wode ni, ọmọbinrin ti wọn n sọ yii gan-an, wọn kan sunmọ ara wọn lásán ni pẹlu Oloogbe, ki i ṣe pe wọn n fẹra wọn.
" Idi tiwọn fi ṣe ikọlu si i ti ẹmi rẹ fi bọ ni ko ye wa rara".
Bẹ̀ẹ̀ ni aburo Oloogbe wi.
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ile igbokupamọsi ni oku naa ṣi wa.
Akọroyin BBC News Yoruba ṣabẹwo sile awọn Abdullahi Saidi ti wọn lo mọ nipa iku naa, to si tun jẹ ile rẹ ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, ṣugbọn ibẹ ti di ahoro, ko seni kan nibẹ rara.
Ninu iwadii lati gbọ pe awọn ẹya Ebira, lati ipinle Kogi, nikan lo n gbe ni agbegbe naa.
Ọlọpaa ṣalaye nipa ẹni ti wọn fẹsun kan, wọn lo ti jẹwọ

Ẹwẹ, atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti fi sita lori ọrọ yii, eyi ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Sunday Abutu, buwọ lu, ṣalaye nipa iku Chukwuemeka ni kikun.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe Abdullahi Saidi ni baba ọmọbinrin to jẹ ọrẹ Oloogbe.
Atẹjade ọlọpaa ṣalaye pe Abdullahi Saidi jẹwọ pe inu oun ko dun si Chukwuemeka tori pe o n fẹ ọmọ oun, wọn ni eyi lo sọ pe o fa a toun fi ṣe ikọlu si i.
Ṣaa, ọrọ naa ti de ile ẹjọ Majisireeti ilu Ado Ekiti, Adajọ si ti paṣẹ pe ki wọn fi Abdullahi ati ẹnikan ti wọn jọ fẹsun kan wọn pamọ si ọgba ẹwọn bi iwadii ṣi n tẹsiwaju














