Ẹ̀gbọ́n ṣekúpa àbúrò nítorí ₦20,000 ni Ondo

Aworan ọkọ to n gbe awọn ẹlẹwọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Eze Elechi Amadi ti jẹ wọ pe oun ṣekupa aburo rẹ, ẹni ọdun mejidinlogun, Otu Ifeanyi nijọba ibilẹ Odigbo nipinlẹ Ondo lasiko awọ owo.

Amadi, wa lara awọn afurasi mọkindinlọgọrun ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣafihan niluu Akure, to jẹ olu ilu nipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bii Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Adebowale Lawal ṣe ṣalaye, imọlẹ tan si iṣẹlẹ naa nigba ti olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ ti waye, Oluwafemi Oladipupo kesi ileeṣẹ ọlọpaa leti pe agba alawọ aro kan ti wọn fi okun dudu ṣo wa niwaju ile rẹ.

Lẹyin iwadii, ileeṣẹ ọlọpaa ṣawari oku Otu Ifeanyi ninu agba alawọ aro naa to wa niwaju ile Oluwafemi Oladipupo.

Dirọmu naa, ni Amadi gbe sori ọkade, to si jabọ lasiko to n gbe lọ pe ki oun lọ ju oku naa sọnu.

Ọwọ ti tẹ afurasi naa bayii, ti iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ki ni iṣẹlẹ ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Alayande Olushola fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe Amadi ṣekupa pe aburo rẹ nitori ẹgbẹrun lọna ogun naira, ₦20,000.

Olushola ni afurasi yii lo mu aburo rẹ to di oloogbe wa si ipinlẹ Ondo, to si fẹsun kan pe o ji owo toto ,₦20,000.

"Lẹyin ọpọ ifọrọwanilẹnu, Amadi jẹwọ pe oun sekupa aburo rẹ, Ifeanyi Otu nitori owo to sọ pe o ji.

"Lati le bo ara rẹ ni aṣiri, o gbe oku naa sinu agba nla, to si gbe sori ọkada lati lọ ju danu sibi to jina.

"Ṣugbọn asiri rẹ tu nigba ti agba ọhun yidanu lori ọkada nigba to n lọ, eyi to ṣafihan oku aburo rẹ.

"Kete ni awọn oṣojumikoro kesi ileeṣẹ ọlọpaa, ti afurasi naa si ti wa ni ahamọ bayii."

Agbẹnusọ ọlọpaa ni awọn ti pari iwadii lori iṣẹlẹ naa, ti afurasi ọhun yoo si foju ba ile ẹjọ laipẹ.