Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ lárìnlọọ̀dù tó jẹ́ agbódegbà fáwọn adigunjalè tó pa bàbá, fipa bá ọmọ rẹ̀ méjì lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Independent Newspaper
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti ṣe afihan awọn afurasí adigunjalè mọkanlelogun, fun ẹ̀sùn pe wọn pa ọkùnrin kan, wọn si tun fi ipa ba awọn ọmọ rẹ obìnrin meji lòpọ̀ n'ilu Ibadan.
Àwọn afurasi naa pa Ọgbẹni Makanjuola Ogedengbe ni abule Apaatuku/Onireke, ni ijọba ibilẹ Lagelu nipinlẹ Oyo.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá nipinlẹ naa, Adewale Osifeso sọ fun iwe iroyin Punch pe awọn afurasí yabo abule naa ni ọjọ kẹrinla, oṣù Karùn-ún, ọdún 2023, nibi ti wọn ti ja awọn ara abule ni olè.
"Asiko naa ni wọn pa Din Ọgbẹni Makanjuola Ogedengbe, ti wọn si tun fi ipa ba awọn ọmọ rẹ obinrin, ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mẹrinla ati mẹ́wàá."
Lasiko iwadii àwọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni àṣírí tu pe awọn afurasí adigunjalè ti wọn n wa tẹlẹ - Ibrahim Rasaq, 31; Abiodun Olalekan, 32; and Abolade Morenikeji, 34, fun ẹ̀sùn ole jija ni agbegbe Ogbere n'ilu Ibadan, naa lo lọ si abule Apaatuku/Onireke.
Ọgbẹni Osifeso sọ pe awọn ọlọ́dẹ adugbo ni anfaani lati pa olori ikọ̀ adigunjalè ọ̀hún, bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn naa yìnbọn mọ ọdẹ kan.
"Ni nǹkan bi aago mẹta aabọ oru lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfà, ni ọwọ tẹ Ọgbẹni Adebayo Salami, to jẹ agbodegba fun ikọ̀ adigunjalè naa."
"Adugbo Ajara, Olorunda, ti ko fi bẹẹ jina si abule Apaatuku/Onireke ni Salami kọ ile si, ti ọwọ́ ọlọ́pàá si tẹ ẹ pe o mọ̀ nipa idigunjale naa."
Lasiko Ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lo jẹwọ fun àwọn ọlọpaa pe oun lo ranṣẹ́ pe àwọn adigunjalè naa lati wa si Apaatuku, nibi ti wọn ti pa Ọgbẹni Ogedengbe, ti wọn si tun fi ipa ba awọn ọmọ rẹ meji lòpọ̀.












