Ondo Mortuary: Pàǹtí ni òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì dà sínú pósí dípò òkú ọmọ
Eto Ìròyìn Kàyééfì ti BBC Yorùbá ti oṣù yìí balẹ̀ bàgẹ̀ lónìí.
Ètò yìí ni a fi ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbẹnu tán, tó ka ni láyà, tó yanílẹnú wo káàkiri àgbáyé bẹ̀rẹ̀ láti orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
- Jesu Oyingbo rèé, pásítọ̀ tó láṣẹ ìbálòpọ̀ lóri ọmọ ìjọ obìnrin
- D.O Fagunwa kú, dúkìá rẹ̀ sì ń fọhùn síbẹ̀, ilé rẹ̀ rèé
- Samuel Ladoke Akintọla jẹ́ Agbẹjọ́rò àti Akọ̀ròyìn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Nàíjíríà
Lọ́sẹ̀ yìí, ilú Akure ní ìpínlẹ̀ Ondo ni BBC Yorùbá tún ti rí Kàyééfì yii o.
Ọ̀rọ̀ òkú ọmọ, òkú ìyá àti olubi ọmọ tí wọ́n gbé tó sì pé lọ sí ilé ìgbókùú pamọ́ sí ṣùgbọ́n tí òkú ọmọ wa di àwátì lọ́jọ́ ìsìnkú ló ṣí ẹnu BBC Yorùbá sílẹ̀ gbáà.
Ẹbí dá ẹ̀bi rù ilé ìwòsàn, ilé ìwòsàn ní ìyá ọmọ ní kò fọwọ́sowọ́pọ̀ ṣugbọn wọn ṣe iṣ abẹ fun aboyun yii lai gba aṣẹ lọwọ ọkọ rẹ tabi idile, lo ba gba ibẹ re salakeji tọmọ tọmọ. O gbẹnu tan o!