YCE Crisis: Kunle Olajide ní áwọn tó déte yíyọ òun ní ákọ̀wé YCE kò lẹ́nu ńbẹ̀

Oríṣun àwòrán, nkirukanistoran
Awuyewuye to n waye lori asaaju ẹgbẹ igbimọ agba Yoruba, YCE ti n gba ọna miran yọ pẹlu bi awọn kan ninu ẹgbẹ ti ṣe jawe lọ rọkun nile fun akọwe ẹgbẹ naa, Dokita Kunle Olajide.
Amọ ṣa, Kunle Olajide ti ni awọn to korajọ yọ oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ tootọ fun idi eyi wọn ko lagbara lati yọ oun.
Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Olajide ni ''ko si ẹnikankan to di ipo mu ninu ẹgbẹ to ṣe ipade kankan loni depo pe wọn yoo wa yọ oun lẹgbẹ.''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakannaa lo ni, ko si nkankan to n jẹ baba agba, eyiun ''senior elder'' ninu igbimọ agbagba Yoruba.
O wa na ika aleebu si alagba Sam Agbede gẹgẹ bi ẹni to lọ ko awọn kan jọ pe, wọn ti ju ọgọrin ọdun lọ, to si ni ''a ko mọ wọn nitori wọn ko si ninu iwe ofin ẹgbẹ''
Olajide ni o da oun loju pe, awọn agbagba ẹgbẹ ni ipinlẹ mejeje ko ni pẹ fesi si ọrọ yii.
Olajide ni oun ko ri iwe kankan gba pe ki oun lọ rọọkun nile lati ọdọ ẹgbẹ YCE, iroyin eke lasan si ni kede to ni wọn le oun kuro ninu igbimọ ẹgbẹ agbaagba Yoruba.
BBC Yoruba tubọ bere lọwọ rẹ boya igbesẹ lati yọ niṣe pẹlu ọrọ to sọ fun BBC Yoruba nipa pe awọn Yoruba lodi si dida agọ Fulani silẹ nilẹ Yoruba ṣugbọn o ni oun ko ro bẹ.
''Agbede kan fẹ joye ni.Mi o ro pe o ni ṣe pẹlu rẹ nitori gbogbo awọn agba ẹgbẹ lo wa nibi ti a ti sọ pe awa Yoruba ko faramọ Ruga Settlement ni ilẹ Yoruba.
O fi kun ọrọ rẹ pe ''awọn eleyi ko ni nnkankan ṣe ni,laipẹ yi awọn to yẹ yoo da wọn loun''
Lọjọbọ ni iroyin gbode pe awọn ọmọ ẹgbẹ YCE kan pamọran pọ lati yọ Dokita Kunle Olajide gẹgẹ bi akọwe ẹgbẹ.
Nibi ipade naa to waye, gẹgẹ bi a ti ṣe riika ni Ilu Ibadan,awọn agbagba ẹgbẹ naa fi ontẹ jan Dansaaki Agbede gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ naa.
Ninu awọn to kọwọrin ni ibi ipade yi la ti gbọ pe Oloye Mike Omoleye,Jibade Oyekan,Adegboye Onigbinde,Ọjọgbọn Adetoun Ogunsheye ati Sam Agbetuyi wa.
Ipade naa lawọn fọwọ si ki Comrade Sam Agbetuyi di ipo akọwe ẹgbẹ mu gẹgẹ bi fidihẹ.














