Police officer raiding illegal cockfight : Àlàyé rèé bí ọlọ́pàá ṣé kàgbákò ikú gbígbóná lọ́wọ́ àkùkọ

Aworan ibi tawọn eeyan ti n fi akukọ ja ni Phillipines lọdun 2011

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Fifi akukọ ja nilẹ Phillipines ko ṣẹṣẹ bẹrẹ

Hmmmn. Eledua ma jẹ ka rinrin arinfẹsẹkọ. Agba adura ma ni.

Ọrọ yii difa farakunrin ọlọpaa ilẹ Phillipines kan ti akukọ tawọn eeyan fi n ja ṣeku pa.

O ya yin lẹnu pe akukọ ṣe iku pa ọlọpaa abi? Ododo kuku ni iṣẹlẹ yii to si waye lagbegbe ariwa Samar.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

Abẹ ti wọn so mọ akukọ naa lẹsẹ lo bẹ kasan arakunrin Christine Bolok nigba tawọn ọlọpaa fẹ lọ mu awọn to n fi akukọ ja.

Ẹjẹ bẹrẹ si ni tu jade lara rẹ lẹyin ti abẹ bẹ ẹ lẹsẹ.

O pọ debi pe wọn sare gbe e lọ si ile iwosan ṣugbọn o gbẹmi mi ki wọn to de ibẹ.

Fifi akukọ ja jẹ nkan ti ijọba fofin de lasiko Coronavirus yi.

Lọpọ igba awọn to n fi akukọ ja a maa so abẹ to mu mọ awọn akukọ lẹsẹ.

Akukọ to ba le fi abẹ ti wọn so mọ ọ lẹsẹ yi bẹ ikeji rẹ lo jawe olubori ninu idije yi.

Ọpọ owo lawọn eeyan a si maa fi ta tẹtẹ lori irufẹ ija akukọ yi ni ilẹ Phillipines.

Aworan akukọ ti wọn so abẹ mọ lẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Akukọ ti wọn so abẹ mọ lẹsẹ tawọn eeyan fi n ja

Ọga ọlọpaa lagbegbe ti iṣẹlẹ yi ti waye,Arnel Apud sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe iṣẹlẹ naa fọwọkanilẹmi to si ni ''o kọja ohun ti eeyan le ṣalaye''

''O jẹ iyalẹnu fun mi nigba ti wọn kọkọ fi to mi leti. Igba akọkọ ree ti maa ri iru iṣẹlẹ bayi lati nkan bi ọdun marundinlọgbọn ti mo ti wa lẹnu iṣẹ yi''

O sọ bakan naa pe oun ti fi ikini ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi ọlọpaa to padanu ẹmi rẹ yi.

Eeyan mẹta, akukọ meje ati awọn nkan ija mii to fi mọ owo ilẹ Phillipines to to dọla mọkanla lọlọpaa ri gba nigba ti wọn yabo ibi ti wọn ti n fi akukọ ja.

line

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Murphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé
Àkọlé fídíò, Snake Market: Àwọn òńtàjà ẹran ejò ní ẹran ejò dùn ju ẹran adìẹ lọ