Kí ló yẹ kí ílẹ̀ India se sí ẹkùn tó pa ènìyàn márùn ún?

India

Oríṣun àwòrán, Forest department

Àkọlé àwòrán, Orílẹ̀-èdè India tó ní ẹranko igbó tó pọ̀jù lágbàáyé ń kojú ìsòrò òhún tó yẹ kí wọ́n se láti kojú àwọn ẹranko igbó to n pa àwọn ènìyàn.

Ẹgbẹgbẹrun awọn oṣisẹ eleto aabo lo n wa ẹkun to n kaakiri orilẹ-ede India, lẹyin to ti pa eniyan marun un.

Ajọ to n bojuto ọrọ igbo lorilẹ-ede naa ti lo orisirisi ẹrọ igbalode lati wa ẹkun to n sa kiri yii.

Iwadii ti fihan wi pe o ti le ni ọgọrun un eniyan to ti padanu ẹmi wọn si awọn ẹranko to ṣekupa wọn, lati Osu Kẹrin, ọdun 2014 si Osu Karun un, ọdun orilẹ-ede India to ni ẹkun to poju lagbaye.

India

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kí ló yẹ kí ílẹ̀ India se sí ẹkùn tó pa ènìyàn márùń?

Amọ, iwadii ni erin ti pa eniyan bi aadọta le lẹgbẹrun, nigba ti ẹkun ti sekupa eniyan mejilelaadọrun.

Iwadii fikun un wi pe awọn ẹranko igbo miran bii amọtẹkun, kinihun maa n le eniyan lati pa wọn.

Ejo ati aja naa ko gbẹyin ninu awọn ẹranko to n sekupa eniyan lọdọọdun.

Ekun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amọ ẹranko ti awọn eniyan bẹru julọ ni ẹkun.

Awọn ara India fẹ ki ẹkun naa wa laaye

Bi o tilẹ je pe ajọ eleto aabo n gbiyanju lati sawari ẹkun naa, awọn olowo ati gbajumọ to fẹran ẹkun n parọwa si ajo eleto aabo lati ma se pa ẹkun naa.

India
Àkọlé àwòrán, Ni Osu Kẹsan an, Ile-ẹjo to gaju ni orilẹ-ede India da ẹjọ to nii se pẹlu ki wọn iyinbọn pa ẹkun naa nu, eleyii to faaye gba ki wọn bẹrẹ si ni wa ẹkun naa pada.

Ajọ naa wa parọwa si awọn eleto aabo lati wa ẹkun naa ri, sugbọn ki wọn gbiyanju lati ma se pa a ayafi to ba wu iwa ipa si wọn lasiko ti wọn ba ri i mu.

Ni Osu Kẹsan an, Ile-ẹjo to gaju ni orilẹ-ede India da ẹjọ to niise pẹlu ki wọn iyinbọn pa ẹkun naa nu, eleyii to faaye gba ki wọn bẹrẹ si ni wa ẹkun naa pada.

Ekun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan to ju ẹgbẹrunmarundinlaadọta lo fọwọ si lori ẹrọ ayelujara Change.org lati bere fun ki awọn ẹsọ alaabo o mu ẹkun naa laaye, lai pa.

Awọn eniyan to ju ẹgbẹrunmarundinlaadọta lo fọwọ si lori ẹrọ ayelujara Change.org lati beere fun ki awọn ẹsọ alaabo o mu ẹkun naa laaye, lai pa.

ekun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amọ, awọn eniyan to n gbe ni agbegbe ti awọn eranko yii pọ si n ran ẹsọ alaabo lọwọ lati le sawari ẹkun naa, ki wọn le fi ni alaafia lagbegbe naa.

Amọ, awọn eniyan to n gbe ni agbegbe ti awọn eranko yii pọ si n ran ẹsọ alaabo lọwọ lati le sawari ẹkun naa, ki wọn le fi ni alaafia lagbegbe naa.

India

Oríṣun àwòrán, Forest department

Àkọlé àwòrán, Orílẹ̀-èdè India tó ní ẹranko igbó tó pọ̀jù lágbàáyé ń kojú ìsòrò òhún tó yẹ kí wọ́n se láti kojú àwọn ẹranko igbó to n pa àwọn ènìyàn.