Ṣé Ifá tó yẹ kó yan Alaafin Oyo àti Soun Ogbomosho tuntun rìnrìnàjò ni? - Oluwo

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi tun ti fọ kengbe ọrọ miran mọlẹ lori ọrọ aṣa yiyan awọn ọba ni ilẹ Yoruba.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni Ọba Akanbi ṣe ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria ninu eyi to ti sọ pe Ifa kọ lo n yan ọba mọ bayii, awọn gomina ni.
Lọtẹ yii ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si BBC News Yoruba, Kabiyesi Oluwo ni gbogbo awọn to ba n duro de ki Ifa yan awọn si ipo ọba yoo duro pẹ bi eeyan to n wo iṣẹju akan leti odo ni.
Ọpọ awọn eekan ọmọ ilẹ Yoruba lo ti fesi si ọrọ akọ ti Oluwo sọ wi pe gomina lo n fi ọba jẹ.
‘Ọmọọba to ba n duro de Ifa lati j’ọba yoo duro pẹ’

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1
Amọ bayii ohun ti Oluwo tun n sọ ni wi pe “awọn ọmọọba ti apọju sinima wiwo n ba finra ni yoo maa duro de ki Ifa kede awọn” gẹgẹ bi ọba.
“Ki lo de ti Ifa ko tii yan Alaafin Ọyọ tabi Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun? Abi Ifa ti rinrinajo ni ki a le tete pe e wale lati wa fun awọn ilu wọnyii ni ọba tuntun.”
Ọba Akanbi ni Eledumare lo n fi ọba jẹ, kii ṣe Ifa. “Bi ipo ọba kan ba ṣi silẹ, awọn to ba fẹ du oye bẹẹ a lọ ba ijọba ni. Gbogbo awọn to ba n duro de Ifa yoo wulẹ duro titi ayeraye ni.”








