Mó tí gbáradì kí Naijiria gbé ipò àgbà ní ilẹ̀ Afrika – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dele Alake
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti ni oun ti ṣetan lati mu Naijiria goke agba ni ilẹ Afrika.
Tinubu sọ eyi lasiko ti aarẹ orilẹede Guinea Bissau, Umaro Sissoxo Embalo ṣe abẹwo si Tinubu ni ile rẹ ni Ikoyi, ni ipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade ti olubadamọran pataki si aarẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati iṣẹ pataki, Dele Alake lo fi eyi lede fun awọn akọroyin ti ileeṣẹ aarẹ.
Alake ni bio tilẹ jẹpe ipade abẹwo idakọnkọ ni aarẹ Embalo wa ṣe, aarẹ naa fi asiko naa gboriyin fun aarẹ Buhari lori akitiyan rẹ lati mu ki Naijiria goke agba.
Bakan naa lo fikun un pe abẹwo naa gba aarẹ laye lati jẹ ki ibaṣepọ to dan mọran wa laarin orilẹede Naijiria ati Guinea Bissau.
Embalo to jẹ olori ajọ ECOWAS gboriyin fun Tinubu fun awọn iṣẹ to ṣe lati osu kan to ti de ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.
Alake ni aarẹ naa wa lati ba ibatan rẹ gẹgẹ bi adari ni ilẹ Afrika ku oriire.
O ni igbesẹ nla ni aarẹ naa n gbe ni ilẹ Naijiria, eleyii to n fa iwuri fun awọn orilẹede miran ni ilẹ Afrika.
O ni eyi n safihan awọn nkan ribiribi ti yoo ṣẹlẹ ni ilẹ Afrika ni aipẹ nitori awọn ti ri orilẹede Naijiria gẹgẹ bi asaaju to n gbiyanju lati mu ayipada rere de ba awọn araalu.
‘’Gbogbo eniyan lo n ri Naijiria gẹgẹ bi awokoṣe to ninu ajọ ECOWAS, ti aarẹ Tinubu si ṣetan lati gbe ipo adari ninu ajọ naa.’’

















