Ṣé lóòtọ́ ni Buhari bẹ Tinubu kó má ṣèwádìí òun àtàwọn tó ba ṣiṣẹ́?

Tinubu and Buhari

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Aarẹ Naijiria ana, Muhammadu Buhari ti sọ pe oun ko sọ fun Aarẹ Bola Tinubu pe ko ma ṣe iwadii awọn to ba oun ṣiṣẹ.

Agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu lo fi ọrọ naa lede ni atẹjade kan loju opo Twitter rẹ.

Ọrọ yii lo jade lẹyin ti iroyin kan sọ pe Tinubu yoo ṣe iwadii iwa ajẹbanu ijọba Buhari amọ yoo yọ Buhari atawọn oṣiṣẹ rẹ kan ṣeyin.

Garba Shehu ni ko si ododo kankan ninu iroyin ọhun.

O ni “iroyin ẹlẹjẹ ni, ẹ majẹ ki a tun maa gba a bi ẹni gba igba ọti.”

“Iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa, ko ju bẹẹ lọ.”

Shehu sọ siwaju si pe ko si ẹnikẹni ninu yara ti Buhari ati Tinubu ti ṣe ipade, nitori naa o ṣoro lati mọ ohun patọ ti wọn ba ara wọn sọ.

“Buhari ko fẹ ki ẹnikẹni yọ oun lẹnu”

Shehu tun sọ pe ohun ti Buhari n fẹ bayii ni isinmi lẹyin to ti pari saa rẹ gẹgẹ bii Aarẹ, ko si fẹ ki ẹnikẹni yọ oun lẹnu tabi lati yọ ijọba tuntun lẹnu.

O ni “o yan lati lọ sile rẹ to wa ni Daura ni ireti pe yoo ni isinmi amọ ọpọ ero lo wa n ki lojojumọ.”

“Eredi ree to tun fi kuro ni Daura lọ si ibomiran to jina rere.”

O pari ọrọ rẹ pe “Oun ti Aarẹ ana n fẹ ni ki awọn eeyan fun ni isinmi, ati pe ki ijọba Tinubu ri aye lati sin awọn araalu lẹyin awọn ileri to ṣe fun wọn.