Ohun pàtàkì tó yẹ́ kóo mọ̀ rèé nípa ojú òpó Threads tó fẹ́ gbadé mọ́ Twitter lọ́wọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ imọ ẹrọ Meta to ni oju opo Facebook ati Instagram ti gbe oju opo tuntun ‘’Thread ‘’jade, eleyii ti Mark Zukerberg ni yoo gba ade mọ oju opo Twitter.

Awọn onimọ nipa oju ẹrọ ni oju opo Threads ṣeeṣe ko mu ọpọlọpọ awọn ololufẹ oju opo Twitter lọ si oju opo tuntun naa nitori awọn igbeṣẹ ti ko ba awọn to n lo oju opo naa lara mu ti Elon Must n gbe jade.

Threads ni yoo gba awọn to n lo laaye lati kọ ọrọ 500 lẹẹkan naa, ti yoo si ni awọn ohun meremere bii ti oju opo Twitter.

Zukerberg ni o le ni miliọnu marun un awọn eniyan to ti buwọlu oju opo naa.

Saaju lo ti sọ pe awọn ni lọkan lati ri pe oju opo naa fa awọn eniyan mọra.

Awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa re e;

Kini awọn ohun meremere ti Threads yoo ni?

Ileeṣẹ Meta ni iwoye awọn ni lati mu awọn ohun meremere ti awọn eniyan ni anfaani si loju opo Instagram, ki wọn si gbe wa si Thread, nibi ti awọn eniyan yoo ti kọ ọrọ daradara.

Bio tilẹ jẹpe Threads da wa ni, yoo ṣeeṣe fun awọn eniyan lati lo oju opo Instagram wọn lati wọ oju opo Threads.

Amọ awọn ti ko ba fẹ gba oju opo Instagram wọle naa le lo lọ si oju opo Threads taarata.

Bakan naa ni awọn eniyan yoo le tẹle awọn to wu wọn ati awọn ti wọn n tele loju opo Instagram tẹlẹ.

Aworan

Bawo ni Threads yoo ṣe ṣiṣẹ?

Ni oju opo Thread awọn eniyan yoo ni anfaani lati fi awọn aworan ati fidio ti wọn n fisi ni Intagram si ibẹ.

Bakan naa ni wọn yoo nianfaani lati fi fidio to to iṣẹju marun un si oju opo naa.

Awọn eniyan yoo maa ri ohun ti awọn to n tẹle wọn n kọ si oju opo wọn.

Bakan naa ni wọn yoo le fi aaye fun awọn ti wọn fẹ ko ‘’mention’’ wọn ti wọn ba n kọ atẹjade si oju opo wọn.

Bio tilẹ jẹpe Meta ni oju opo tuntun naa yoo dabi Instagram amọ awọn eniyan ni ọna lati gbade mọ Twitter lọwọ ni.

Awọn orilẹede wo ni yoo lanfaani lati lo oju opo ‘’Threads’’?

Ileeṣẹ Meta ni awọn orilẹede ni ilẹ Yuroopu ko ni tii ni anfaani si oju ẹrọ naa lasiko yii nitori awọn ofin to rọmọ lilo oju opo imọ ẹrọ.

Bakan naa ni wọn ni awọn eniyan lati awọn orilẹede to le ni ọgọrun, ti Niajiria ati Ilẹ Gẹẹsi wa ninu rẹ yoo ni anfaani lati lo loju opo wọn.

Amọ ileeṣẹ naa ni ijiroro n lọ lọwọ pẹlu Ajọ Iṣọkan Ilẹ Yuroopu.

Eyi n waye lasiko ti Elon Must gbe gebndeke lori awọn iye igba ti awọn eniyan le tweet loju ẹrọ naa.

Awọn onimọ ni awọn ofin tuntun yii yoo fun awọn eniyan ni anfaani lati lọ si ‘’threads’’ ni awọn ọna to wu wọn.

Elon Musk to ni Twitter ni oun gba ilẹẹjọ́ lọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ oju opo Twitter ti ni awọn n gbe ileeṣẹ Meta lọ si ileẹjọ lori ẹrọ tuntun ‘’Threads’’ ti wọn gbe jade.

Elon Musk ni oun ko bẹru ifigagbaga amọ iyanjẹ ni oun ko fẹ.

Amọ ileeṣẹ Meta ni awọn ko lo awọn oṣiṣẹ Twitter to kuro lati da ‘’Threads’’ silẹ.

Meta ni o kere tan miliọnu ọgbọn awọn eniyan ni wọn ti download oju opo tuntun naa si ori ẹrọ wọn.

Onimọ nipa iroyin imọ ẹrọ ni BBC, James Clayton jabọ pe bi awọn iroyin ṣe n wọle si oju opo tuntun naa jọ ti oju opo Twitter.