Ẹ̀yin ará ìpínlẹ̀ Ondo, mò ń bọ̀ láìpẹ́, mọ dúpẹ́ fún àdúrà yín- Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti fi idunnu rẹ han si awọn ọmọ Naijiria fun aduroti wọn lasiko to sẹ aisan.
Ninu atẹjade ti gomina Akeredolu fi lede gba ọwọ Kọmiṣọna fun eto iroyin rẹ, Bamidele Ademola-Olateju lo ti sọrọ idupẹ naa.
Akeredolu dupẹ lọwọ awọn ara ipinlẹ Ondo fun adura wọn nigba gbogbo fun anfaani lati wa ni alaafia pẹlu ilera pipe.
O ni iru ifẹ yii si oun mu inu oun dun to si fun oun ni idunnu lati duro ni ori ẹṣẹ oun, to si jẹ moriya fun oun lati ṣe moriya fun oun lati pada si ẹnu iṣẹ.
Bakan naa ni gomina ọun dupẹ lọwọ aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ati gbogbo awọn alabaṣiṣẹ rẹ to fi mọ awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC, awọn gomina akẹgbẹ rẹ ati awọn aṣofin ni ile igbimọ aṣofin Naijiria.
Gomina Akeredolu ni ara oun yagaga lati pada si ọdọ awọn eniyan rẹ ni kete ti dokita rẹ ba ti buwọlu.
O dun mọ wa lati gbọ pe gomina Akeredolu wa ni alaafia - Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo ti fi ayọ wọn han si ikede pe alaafia ni gomina ipinlẹ Ondo wa ati pe ara rẹ ti balẹ.
Ninu atẹjade ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC buwọlu ni awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun to fun gomina naa ti ilera rẹ ti gberu si.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ naa fi ifẹ han si gomina naa, ti wọn si dupẹ lọwọ rẹ fun atilẹyin awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo.
Bakan naa ni wọn kesi gomina naa lati ri pe oun sinmi daradara, bio tilẹ jẹpe gbogbo eniyan lo mọ pe gomina ọun fẹran iṣẹ ṣisẹ.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ naa wa kesi awọn ara ipinlẹ Ondo lati tubọ maa gbadura fun gomina naa fun ilera pipe.
NLC ṣapejuwe gomina naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn gomina to fakọyọ ni asiko rẹ.

















