Ìwádìí fihàn pé nínú ilé ìwòsàn 88 ní Khartoum, 61 nínú wọ́n ní wọn tí ṣèkọlù sí nínú ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Sudan

Àkọlé fídíò, Ìwádìí fihàn pé nínú ilé ìwòsàn 88, 61 ní àwọn ológún ṣèkọlù ní Khartoum, ní ilẹ̀ Sudan
Ìwádìí fihàn pé nínú ilé ìwòsàn 88 ní Khartoum, 61 nínú wọ́n ní wọn tí ṣèkọlù sí nínú ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Sudan
Aworan

Iwadii ti BBC African Eye gbe jade fihan pe ikọ ologun orilẹede Sudan ati ikọ eleto aabo RSF to n koju ija si ara wọn ni Sudan ru ofin to rọ mọ ijagun.

Iwadii fihan pe wọn ṣekọlu si awọn ileewosan, ti wọn si tun dana sun ile igbe awọn nọọsi ti wọn n tọju awọn araalu.

Iwadii BBC African Eye fihan pe ninu ileewosan mejidinlaadọrun to wa ni ilu Khartoum ni Sudan, mọkanlelọgọta ninu wọn lo ti wa titi pa lẹyin ti awọn ikọ ologun ju ado oloro si awọn ileewosan yii.

Awọn dokita ti wọn ba BBC sọrọ ni wọn tun dunkoko mọ awọn dokita, ti wọn si tun tẹ orukọ wọn jade lati pa wọn.

Bakan naa ni awọn araalu ti wọn ni lati sa asala fun ẹmi wọn ni ko si omi mimu fun awọn eniyan lati lo oogun wọn, bẹẹni ko si ina ijọba, ti ohun gbogbo si da ahoro nibẹ.

Osu Kẹrin, ọdun 2023 ni ija bẹ silẹ nibẹ, ti awọn ikọologun mejeeji si bẹrẹ si ni kọ oju ija si ara wọn