Ṣé lóòótọ́ ni pé àrá sán pa àwọn ajínigbé ní Kwara? Àbọ̀ ìwádìí rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Journalist
Láìpẹ́ ọjọ́ yìí ni fídíò kan gba orí ayélujára níbi tí àwọn kan ti ń ṣe àfihàn òkú àwọn ènìyàn méjì kan tí àrá sán pa.
Ohùn tó ń jáde nínú fídíò náà sọ wí pé àwọn ajínigbé tó ń da agbègbè ìlú Oro-Ago ní ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn tí àrá sán pa náà.
Ohun tí a tún gbọ́ nínú fídíò náà ni pé ọwọ́ tẹ àwọn mìíràn tí àwọn kò kú àti pé àwọn ènìyàn náà jẹ́wọ́ wí pé àwọn ni àwọn lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó wáyé ní ìlú Iwo láìpẹ́ yìí níbi tí wọ́n ti jí pásítọ̀, alákòóso ilé epo kan àti bàbá ọlọ́dẹ kan gbé.
Ènìyàn méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé náà lọ nígbà tí àwọn ajínigbé náà pa bàbá ọlọ́dẹ náà àti ènìyàn kan lásìkò tí wọ́n ń kó àwọn ènìyàn tí wọ́n jí gbé náà lọ lọ́nà inú igbó.
Mílíọ̀nù márùn-ún náírà ni pásítọ̀ àti máníjà ilé epo san láti fi rí ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n lo ọjọ́ mẹ́rin sí ọjọ́ márùn-ún ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà.
Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara ti ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni gbogbo nǹkan tí wọ́n ń sọ nínú fídíò náà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara, Ajayi Okasanmi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní lẹ́yìn tí fídíò náà gbòde ni Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Ebunoluwarotimi Adelesi ní kí àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Okasanmi ní ìwádìí àwọn fi hàn pé àwọn ọmọdé méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá àti ọdún méjìlá ni àwọn tí àrá sán pa náà.
Ó ṣàlàyé pé bàbá àwọn ọmọdé náà tó jẹ́ darandaran ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn.
Ó ní lóòótọ́ ni àrá sán pa àwọn ènìyàn méjì àmọ́ wọn kìí ṣe ajínigbé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń gbe kiri lórí ayélujára.
"Fún ìdí èyí, a gba àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara ní ìmọ̀ràn láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn náà."
Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé àwọn afurasí ajínigbé mẹ́rin tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ ṣáájú ní agbègbè Oro-Ago ni àwọn ti gbé lọ sílé ẹjọ́ tí wọ́n sì ti ń káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ níwájú ìjọba.
Àwọn méjì nínú awon tí ajínigbé gbé ní Isanlu-Isin gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, KWARA POLICE
Okasanmi tún tẹ̀síwájú pé ní ọjọ́bọ̀ ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé mìíràn tún wáyé ní Isanlu-Isin, ìpínlẹ̀ Kwara bákan náà.
Ó ní àwọn mẹ́rin kan - Dipe Ajayi, Kunle Abolarin, Femi Abolarin àti Femi Ajayi ni wọ́n kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé láàárín ìlú Ijara-Isin àti Isanlu-Isin.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ni ikọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé, àwọn ọlọ́dẹ àtàwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí wọ́n sì rí ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oke Olatunji gbà sílẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta náà ni Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá fúnra rẹ̀ tún kó àwọn ọlọ́pàá sòdí láti lọ dọdẹ àwọn ajínigbé náà tí àwọn sì tún rí ẹlòmíràn, Femi Ajayi gbà kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà.
Okasanmi ní Femi Ajayi tí wà ní ilé ìwòsàn Isanlu-Isin níbi tó ti ń gba ìtọ́jú nítorí ó fara gba ọta ìbọn.
Ó fi kun pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara fi àsìkò náà ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọlọ́dẹ, àwọn fijilanté àtàwọn baálẹ̀ ìlú kọ̀ọ̀kan ṣe ìpàdé ní ààfin Olusin ti Isanlu-Isin lójúnà à ti lè wá ojútùú sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó ń wáyé ní lemọ́lemọ́ ní agbègbè náà.
Ó fi kun ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti lè gba àwọn ènìyàn yòókù kalẹ̀ ní àhámọ́ àwọn ajínigbé tí wọ́n wà.
Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé àwọn ajínigbé náà fi àwọn mẹ́ta yòókù sílẹ̀ tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kọ̀ láti padà lẹ́yìn wọn.















