Makinde sọ ìdájọ́ ikú di ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin l’Oyo

Aworan Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ṣiju aanu wo ẹlẹwọn mẹrin ti wọn dajọ iku fun un ti o si paṣẹ pe ki ijiya wọn di ẹwọn gbere.

Bakan naa ni Gomina Makinde paṣẹ idasilẹ ẹlẹwọn mẹwaa mii ni awọn ọgba ẹwọn ipinlẹ Oyo.

Adari ọgba ẹwọn ni ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Abdulraheen Salami, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọgba ẹwọn, Ọgbẹni Olanrewaju Anjorin.

Ọgbẹni Salami tun fidi rẹ mulẹ pe Makinde tun ṣe adinku ọdun awọn ẹlẹwọn mii nigba ti o tun paṣẹ idasilẹ awọn mẹrin kan ṣugbọn pẹlu ọrọ asọọlẹ.

Awọn mẹrin ọhun ni wọn jẹ akẹkọọ ni fasiti NOUN eyun n ni National Open University, ti wọn yoo si gba ominira ti wọn ba ti pari ẹkọ wọn.

Adari ọgba ẹwọn ni ipinlẹ Oyo ni ‘’igbesẹ gomina yoo fawọn ẹlẹwọn ni iwuri lati maa kọ iṣẹ ọwọ tabi ka iwe pẹlu awọn anfaani to wa fun wọn lọgba ẹwọn.’’

O ni oriṣiiriṣii eto ẹkọ lo wa fawọn ẹlẹwọn lati kọ ni ọgbọn ẹwọn niwọn igba ti wọn ba wa nibẹ.

O kere tan ẹlẹwọn 1,800 lo wa ni ọgba ẹwọn niluu Ogbomoso, Ibadan ati ilu Oyo.

Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ti bẹrẹ iṣẹ lori awọn ti gomina ipinlẹ Oyo paṣẹ pe ki wọn da silẹ.