Ilééṣẹ́ Ọlọ́pàá dá ọlọ́pàá méjì dúró fún ẹ̀sùn ìdigunjalè

Aworan

Awọn ọlọpaa meji kan ti orukọ wọn n jẹ Sunday Adetoye ati Ogunleye Stephen ti wọn sisẹ fun igun ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2 Command ni Onikan nipinlẹ Eko, ni wọn ti gbẹwu lọrun wọn fun ẹsun idigunjale.

Awọn ẹsun mii ti wọn fi kan awọn ọlọpaa naa ni ẹsun iwabajẹ ati sise isẹ ni ọna ti ko ba ofin mu.

Asẹ yii lo jade lati ẹnu Oluranlọwọ Ọga agba fun Ileeṣẹ ọlọpaa , to n sakoso Zone 2, AIG Mohammed Ali lẹyin ti wọn farahan niwaju igbimọ to gbọ ẹsun naa.

Adetoye pẹlu nọmba idanimọ 279495 ati Stephen pẹlu nọmba idanimọ 223521, ati awọn meji kan lati inu ikọ fijilante ti orukọ wọn n jẹ Semiu Afisu ati Abidoye Femi, dẹrẹba ti orukọ n jẹ Charles John ni wọn jọ lẹdi apo pọ lati jale ni agbegbe kan ni Obada-Oko nipinlẹ Ogun lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2023.

Ibọn meji ati ọta ibọn ni wọn ka mọ wọn lọwọ lẹyin ti wọn yabo ile kan to jẹ ti Taiwo Monsuru ati Akintola Sunday lai gba asẹ, ti wọn si ko foonu Iphone marun-un, Samsung kan, Tecno kan ati ẹrọ ayarabiasa laptop meji.

Nigba ti o n salaye bi ọwọ se tẹ awọn afurasi naa, SP Umma Ayuba ni ọwọ awọn ọlọpaa to wa ni Ifo lo tẹ wọn.

Eyi waye lẹyin ti awọn olugbe agbegbe kesi wọn nipa ohun to sẹlẹ, ti wọn si sapejuwe iru ọkọ ti awọn adigunjale naa gbe wa.

“Eyi lo ran awọn ọlọpaa lọwọ lati mu awọn adigunjale naa, ti olori wọn ASP Ajayi Victor si ti fẹ sẹ fẹ.”

AIG ti wa palasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ile ẹjọ, to si tun kilọ fun awọn ọlọpaa yooku lati yago fun iwa ti yoo tabuku si asọ ọlọpaa.