Àwọn àwòrán láti ibi ìsìnkú Adedeji Aderemi Olofa Ina

Adedeji Aderemi Olofa Ina

Wọn ti sin oku agba oṣere, Oloye Adedeji Aderemi 'Olofa Ina' to di oloogbe ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024.

Ile rẹ to wa ni agboole Fiwasay niluu Ede, nipinlẹ Osun ni wọn sin si, lọjọ Ẹti, ọjọ Karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2024.

Ni nnkan bi aago mẹrin abọ Irọlẹ ni wọn gbe oku oloogbe Aderemi wọ ilẹ, lẹyin ti awọn Alfa kirun si lara ni ilana ẹsin Isilaamu.

Ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni.

Yatọ si ẹbi ati ara, awọn oṣere ẹgbẹ rẹ naa peju sibi eto isinku naa.

Lara awọn oṣere ti akọroyin BBC ri ni Olaiya Kayode 'Aderupoko', Abdullateef Babatunde 'Fokoko', Oluwatoyin Oladiran 'Abeni Agbon', ati awọn mii.

Ẹ wo diẹ ninu awọn aworan to sọ bi eto naa ṣe lọ:

Owurọ ọjọ Ẹti ni ẹbi oloogbe Aderemi gbe iwe kalẹ fun awọn alejo to wa n ki wọn lati kọ ọrọ iranti nipa rẹ
Àkọlé àwòrán, Owurọ ọjọ Ẹti ni ẹbi oloogbe Aderemi gbe iwe kalẹ fun awọn alejo to wa n ki wọn lati kọ ọrọ iranti nipa rẹ
Diẹ lara awọn iyawo oloogbe
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn iyawo oloogbe
Akọbi oloogbe l'obinrin
Àkọlé àwòrán, Akọbi oloogbe l'obinrin, Arabinrin Suarau Adedeji Aderemi sọ fun BBC pe eeyan daadaa ni wọn mọ baba oun si ni adugbo.
Bayii ni wọn ṣe di oku pẹlu aṣọ funfun, ki wọn o to sin-in
Fokoko ati Digboluja
Àkọlé àwòrán, Awọn agba oṣere, Abdullateef Babatunde 'Fokoko' ati Tafeeq Adewale 'Digboluja', wa nibi eto isinku naa
Bobo B
Àkọlé àwòrán, Alhaji Ayobami Olabiyi ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Bobo B to tun jẹ Akowe fun ẹgbẹ TAMPAN ni Naijiria
Aderupọkọ
Àkọlé àwòrán, Arakunrin Olaiya Kayode ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Aderupọkọ ṣapejuwe Olofa Ina gẹgẹ bi alaanu fun gbogbo eeyan ati awọn oṣere tiata.
Lati owurọ kutu ni ero ti n peju sile oloogbe lati daro rẹ
Àkọlé àwòrán, Lati owurọ kutu ni ero ti n peju sile oloogbe lati daro rẹ
Eto adura waye fun oloogbe ṣaaju isinku rẹ
Àkọlé àwòrán, Eto adura waye fun oloogbe ṣaaju isinku rẹ
Lara awọn agba oṣere to wa nibi eto isinku naa
Àkọlé àwòrán, Lara awọn agba oṣere to wa nibi eto isinku naa