Sinimá Funke Akindele, 'A Tribe Called Judah' tó mi ìgboro tìtì fi ìtàn lélẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe pa ₦1bn wọlé

Aworan sinima Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, FilmOne Entertainment

Fiimu Nollywood kan ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi fiimu akọkọ ni Naijiria ti yoo pa biliọnu kan Naira wọle lati awọn ile iworan sinima ni Naijiria.

Owo yi ṣe dede $1.1m tabi £900,000.

Ọsẹ mẹta ni fiimu A Tribe Called Judah fi pitu yi lati ọwọ ilumọọka oludari fiimu ati oṣere nii Funke Akindele.

Funke Akindele ti wa fi ikini ranṣẹ si awọn ololufẹ rẹ fun aṣeyọri yi.

Loju opo ayelujara Instaagram rẹ, ilumọọka onisinima naa fi imoore rẹ han to si sọ pe ''O ṣe Ọlọrun! Naijiria mo dupẹ! Ghana mo dupẹ''

Aṣeyọri yi ti wa fi ẹsẹ oṣere ẹni ọdun mẹrindinlaadọta yi rinlẹ gẹgẹ bi oṣere Nollywood to pa owo julọ pẹlu fiimu rẹ.

Bi 'A Tribe Called Judah' ṣe n ba lọ, o dabi ẹni pe yoo bo awọn fiimu lati ilẹ okere Hollywood mi ti wọn ṣafihan wọn ni sinima Naijiria mọlẹ nipa iye to pa wọle.

Black Panther: Wakanda Forever lo ṣaaju di ipo yi mu tẹlẹ gẹgẹ bi fiimu to pawo wọle julọ ni sinima Naijiria.

Ileeṣẹ to n ṣe alabapin fiimu naa FilmOne Entertainment sọ pe ''kii kan ṣe ọrọ iye awọn to wo fiimu yi lo ṣe pataki bi kii ṣe pe agbara itan ti wọn sọ ninu rẹ ati igbelarugẹ aṣa ati ifarajin sinima Nollywood ni Naijiria''

Ileeṣẹ naa kan saara si Akindele to si ni o ti gun oke agba bayii gẹgẹ bi onkọtan ere sinima ni Naijiria.

Jakejado ni awọn onwoye n gboṣuba kare fun fiimu naa loju opo awọn to mọ riri sinima.

Fiimu yi ṣafihan itan abiyamọ ọlọmọ marun un kan to n koju inira to pete lati ja ile ifowopamọ kan lole.

Funke Akindele sọ pe igbiyanju iya to bii lo jẹ gẹgẹ bi iwuri lati kọ itan yi.

Mama rẹ ti di oloogbe.