Ṣé àwọn afurasí mẹ́ta táwọn ọlọ́pàá ṣàfihàn wọn ló wà nídìí Gistlover blog ní tòòtọ́ọ́?

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti ṣe afihan awọn afurasi ọkunrin mẹta eyi ti wọn sọ pe awọn lo wa nidi ikanni ori ayelujara Gistlover.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ tẹ wọn afurasi mẹta naa latari iwe ipẹjọ ti Arabinrin Seye Oladejo kọ, ninu eyi to ti fẹsun igbijmọpọ lati ṣeeyan nibi, idunkoko mọ ni lori ayelujara ati idunkoko lati gbẹmi eeyan mọ ikanni ori ayelujara Gistlover.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ACP Olumuyiwa Adejobi fi sita, o darukọ awọn mẹta naa gẹgẹ bii Adebukola Kolapo, Nnedum Micheal Somtomchukwu ati Isaac Akpokighe.
ACP Adejobi ni ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ni Kolapọ jẹ, ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn ni Somtomchukwu, nigba ti Akpokighe jẹ ọmọ ọgbọn ọdun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹtẹẹta yii jọ n ṣiṣẹ pọ lori Gistlover blog lojoojumọ.
"Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn ti n lo ikanni Gistlover fun ibanillorukọ jẹ ati idunkoko mọ ni lori ayelujara fun ọpọ ọdun bayii."
Ọlọpaa ni lasiko ifọrọwanilẹnuwo, ni awọn afurasi naa sọ ipa ti wọn ko ninu iditẹ mọ eeyan, ti ọrọ wọn si ti ṣe kin ọpọ ẹri to wa nilẹ lẹyin.
"Afurasi akọkọ Kolapo ti inagijẹ rẹ n jẹ Omo oba Gistlover lo wa nidii ida ọgọrin ninu ọgọrun un iroyin to wa lori Gistlover.
" Gẹgẹ bii oṣiṣẹ ikanni Gistlover, ti o si ti jẹ anfaani oriṣiiriṣii ẹbun owo ati ọkọ, Kolapo lo maa n ṣiṣẹ lori wiwa iroyin ati atunkọ iroyin to fi mọ idunkoko mọ ni eyi ti wọn ṣe fun olupẹjọ Dokita Oladejo."
O ni Kolapo tun kopa ninu gbigbe owo lati ibikan lọ si ibo miran ni oniruuru ọna.
Somtochukwu to jẹ afurasi keji ni ọlọpaa sọ pe o kopa ninu igbimọpọ dunkoko ati ditẹ mọ eeyan lori ayelujara.
Oun ni o maa n lo ikanni tiẹ fun iroyin ti Gistlover ba ti yọ kuro tori awọn agbofinro lati le ma jẹ ki ọwọ ọlọpaa tẹ Gistlover.
Afurasi kẹta, Akpokighe to n gbe ni Igando niluu Eko ni tiẹ dabi ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria eleyii to bẹrẹ si ni ṣe bii Gistlover lẹyin to ri owo gọbọi to wa ninu iroyin ofege, idunkoko mọni ati ibani-lorukọjẹ lori ayelujara.
Oun lo maa n gbe ọpọ iroyin Gistlover to fi mọ iroyin ibanilorukọjẹ ati idunkoko mọ ẹmi olupẹjọ atawọn ọmọ Naijiria mii,’’ ACP Adejobi ṣalaye.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹtẹẹta ni yoo foju ba ile ẹjọ ti iṣẹ iwadii ọlọpaa ba ti pari.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Gistlover gbana jẹ lori bawọn ọlọpaa sẹ mu afurasi mẹta
Ninu esi rẹ si afihan awọn afurasi mẹta tawọn ọlọpaa ṣe, Gistlover ti sọ oko sawọn ọlọpaa ati olupẹjọ lori igbesẹ wọn.
O ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ wi pe wọn fẹ fi awọn afurasi mẹta ti wọn mu gbayi loju awọn eeyan lasan ni.
O beere lọwọ awọn ọlọpaa pe ki wọn mu ẹri daju wa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn afurasi mẹta yii lo wa nidii ikanni Gistlover ni tootọọ.
O ni ati ọlọpaa ati olupẹjọ ni yoo na owo wọn danu lasan nile ẹjọ lori ọrọ naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















