A ò ṣàwárí ayédèrú ọ̀jọ̀gbọ́n 100 ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga - NUC

NUC

Oríṣun àwòrán, NUC

Àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìyẹn National Universities Commission, NUC ti ní ìròyìn òfégè ni pé àjọ NUC ṣàwárí àwọn ayédèrú ọ̀jọ̀gbọ́n ọgọ́rùn-ún ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì.

NUC ní ìròyìn tó jìnà sí òótọ́ ni àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára kan ń gbé kiri àti pé àwọn kò lè gbé irú ìr]oyìn bẹ́ẹ̀ síta láì kàn sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Àtẹ̀jáde tí igbákejì ọ̀gá àgbà NUC tó wà nídìí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́, Noel Abiodun Saliu fi síta ní kí àwọn ènìyàn má kọbi ara sí ìròyìn náà rárá àti pé kìí ṣe láti àjọ àwọn ni ìròyìn náà ti jáde.

Saliu ní àwọn kan tí wọ́n ní èròńgbà láti ba orúkó àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ọ̀rọ̀ kàn jẹ́ ni ó ṣeéṣe kí wọ́n wà nídìí ìròyìn náà àti pé wọ́n tún fẹ́ fi tàbùkù àjọ NUC ni.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n gbé orúkọ jáde nínú ìròyìn òfégè náà ni wọ́n ti ń fèsì sí ìròyìn náà pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa ìròyìn náà.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga náà ló ti ń sọ̀rọ̀ pé àwọn orúkọ tó wà nínú ìròyìn náà kò ṣiṣk ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ àwọn rí, tí àwọn kò sì ní ìmọ̀ nípa wọn rárá.

Ó wá rọ àwọn ènìyàn láti má gba ìròyìn náà gbọ́ àti pé kí wọ́n máa ṣèwádìí àwọn ìròyìn tí wọ́n bá kà lórí ayélujára dáradára kí wọ́n tó gbà á gbọ́.

Saliu fi kun p;é ìtàkùn ayélujára àwọn wà fún gbogbo ènìyàn láti ṣe àyẹ̀wò ìròyìn tí wọ́n bá rí nípa àwọn.

Ìwádìí wa fi hàn pé ìròyìn tí àjọ NUC ti fi síta lọ́dún 2019 ni àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbé kiri lásìkò yìí.