'Inú ọmọ mi yóò dùn pé a fi eérú rẹ ranṣẹ́ sínú òṣùpá'
'Inú ọmọ mi yóò dùn pé a fi eérú rẹ ranṣẹ́ sínú òṣùpá'

Awọn eeyan kan ma n sọ pe didun ni iranti olododo, paapaa lati fi daro ẹni wọn to di oloogbe.
Oriṣiriṣi nnkan si ni wọn ma n ṣe gẹgẹ bi àmì, ti orukọ ẹni naa ko fi nii parun.
Fun ẹbi Liam Anand, ọdọmọkunrin to ku, ẹbi rẹ fẹ fi eérú rẹ ranṣẹ sinu oṣupa fun iranti.
Iya rẹ, Nadine Anand, sọ fun BBC pe o da awọn loju pe inu Liam yoo dun to ba ri nnkan ti awọn ṣe.
O ni idunnu ni yoo jẹ fun ẹbi awọn pe ẹya ara rẹ wa ninu oṣupa.
Liam ku ninu ijamba ọkada nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun.





