Ìyàwó ilé méjì dèrò ẹ̀wọ̀n fún fífi PoS ta owó náírà tó tó N3.8m àti N1.6m

Oríṣun àwòrán, EFXX/ X
Awọn obinrin meji kan, Folake Adeoti ati Modupe Adewuyi, ti gba idajọ ẹwọn ọdun kọọkan bayii, fun tita owo naira.
Gẹgẹ bi ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ati fifi abuku kan naira ṣe ṣalaye, iwa to lodi sofin Banki apapọ Naijiria ni lati maa ta owo naira.
Ninu atẹjade ti EFCC fi si oju opo X rẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un ọdun 2025 yii, wọn ṣalaye pe N3.85m lowo tawọn ba lọwọ Adeoti, to n ta.
Ni ti Adewuyi, N1.6m loun ko dani.
Awọn obinrin mejeeji n ta owo naa lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025, lọwọ ba wọn.
Agbegbe gbọngan kan to gbajumọ niluu Eko, ni Jobi Fele Way, Alausa, lọwọ ti ba wọn, bi EFCC ṣe sọ.
Báwo lọ̀rọ̀ ṣe dé ilé-ẹjọ́?
Ẹka EFCC nipinlẹ Eko lo fi oju awọn olujẹjọ mejeeji ba kootu lọjọ Ẹti, ọjọ keji, oṣu Karun-un ọdun 2025.
Agbefọba lori ẹjọ naa, Z.B Atiku, tẹti gbọ alaye awọn olujẹjọ, nibi ti awọn mejeeji ti sọ pe awọn jẹbi ẹsun naa.
Bakan naa lo ko owo ti wọn gba lọwọ wọn silẹ gẹgẹ bi ẹri .
Agbefọba fi kun un pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti ọwọ yoo ba Adeoti ni tiẹ fun ẹsun yii kan naa.
O ni EFCC ti kọkọ mu un ri, to si foju kan kootu niwaju Adajọ Ibrahim Kala.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Yellim Bogoro, ju Folake Adeoti si ẹwọn ọdun kan lai si aaye owo itanran.
Bakan naa lo ran Modupe Adewuyi lẹwọn ọdun kan, ṣugbọn o fi anfaani owo itanran idaji miliọnu naira silẹ fun un.
Adajọ Bogoro paṣẹ pe ẹrọ POS ati owo ti wọn gba lọwọ awọn olujẹjọ mejeeji ti di tijọba apapọ Naijiria.
Tita owo naira, paapaa pẹlu owo to pọ bi eyi, lodi si ofin Naijiria, awọn tọwọ ba tẹ ko si ni i lọ lai jiya bi EFCC ṣe sọ.














