A ṣe àṣìṣe fífi ẹ̀sùn jìbìtì kan NELFUND- ICPC

Aworan osisẹ ICPC

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC ti kede pe awọn ṣe asiṣe nipasẹ fifi ẹsun kan ajọ to n ri si ẹyawo fun awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria, NELFUND lori siṣe owo ilu mọkumọku.

Ṣaaju ni ICPC ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori awọn kudiẹkudiẹ to n waye latari bi awọn fasiti ṣe n pin ẹyawo awọn akẹkọọ ni Naijiria.

Iwadii yii bẹrẹ lẹyin ti iroyin sọ pe awọn ile ẹkọ giga kan n yọ lara owo to yẹ ko tẹ awọn akẹkọọ naa lọwọ to bẹẹ ti owo ti iye rẹ to ₦71bn fi poora.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn ile ẹkọ kan n yọ owo ti iye rẹ wa laarin ₦3,500 si ₦30,000 lori akẹkọọ kọọkan.

Nigba to n ba BBC sọrọ, alaga ICPC, Musa Aliyu ni iwadii awọn ko da lori ajọ NELFUND rara ṣugbọn o da lori awọn ile ekọ giga fasiti kan ti wọn fura si pe wọn ṣe owo awọn akẹkọọ mọkumọku.

"NELFUND ti fi owo ile ẹkọ ransẹ si awọn ile ẹkọ yii, ati awọn owo igbayegbadun awọn akẹkọọ si lọ si ọdọ awọn akẹkọọ."

Aliyu ni awọn akẹkọọ ni pẹlu bi wọn ṣe ti gba owo ti wọn, awọn ile ẹkọ wọn yari pe wọn ko ti ri owo ile ẹkọ wọn. Koda awọn ile ẹkọ tun gba ju bi o ṣe lọ.

O fikun pe owo kankan o sọnu lati ọwọ NELFUND. "Iwadii wa da lori bi awọn ile ẹkọ kan ṣe na owo ilu mọkumọku— ki ṣe NELFUND. Asiṣe ni, ti a si ti bọ sita sọrọ nipa rẹ."

Báwo ni ₦71bn ṣe pòórá nínú owó tí ìjọba ń yá awọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Naijiria? ICPC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

ICPC

Oríṣun àwòrán, ICPC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC, ti bẹrẹ iwadii lori awọn kudiẹkudiẹ to n waye latari bi awọn fasiti ṣe n pin ẹyawo awọn akẹkọọ ni Naijiria.

Iwadii yii lo bẹrẹ lẹyin ti iroyin sọ pe awọn ile ẹkọ giga kan n yọ lara owo to yẹ ko tẹ awọn akẹkọọ naa lọwọ to bẹẹ ti owo ti iye rẹ to ₦71bn fi poora.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, niṣẹ lawọn ile ẹkọ n yọ owo ti iye rẹ wa laarin ₦3,500 si ₦30,000 lori akẹkọọ kọọkan.

Eto ẹyawo naa ni ijọba apapọ gbe kalẹ labẹ eto NELFUND.

Ajọ naa sọ ninu atẹjade kan pe "Ajọ Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission (ICPC) ti bẹrẹ iwadii lori awọn kudiẹkudiẹ to yi eto ẹyawo ti ijọba n ṣe labẹ eto Nigeria Education Loan Fund (NELFUND) ka."

Agbẹnusọ ajọ naa, Demola Bakare sọ pe alafo wa laarin akọsilẹ bi wọn ṣe pin owo naa.

Bakare ni "Bo tilẹ jẹ pe ₦100b ni ijọba gbe kalẹ fun eto naa, ₦28.8b pere ni wọn tii pin fun awọn akẹkọọ, nigba ti wọn ko le ṣalaye ibi ti ₦71.2b wọlẹ si."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Atẹjade naa tẹsiwaju pe ICPC ti kọwe si gbogbo awọn ti ọrọ pinpin owo naa kan lati wa ṣalaye ipa ti wọn ko ninu rẹ.

Lara awọn ti ICPC ti kesi ni ọga agba ajọ to n si ri ọrọ eto iṣuna ni Naijiria, oluṣiro agba ni Naijiria atawọn oṣiṣẹ kan ninu ile ifowopamọ CBN.

O sọ siwaju si pe wọn tun fi iwe pe alaga NELFUND lati pese ẹri to dantọ lori iwadii naa.

ICPC ni lọwọ yii, ₦44,200,933,649.00 ni wọn tii pin ninu owo naa si awọn akẹkọọ nile ẹkọ giga 299.

Ninu awọn ile ile ẹkọ 299 yii, akẹkọọ 293,178 lo ri owo naa gba.

ICPC fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni iyatọ wa ninu owo ti ijọba gbe jade ati owo to tẹ awọn akẹkọọ lọwọ, nitori naa, iwadii to peye yoo waye, ajọ naa yoo si jẹ ki araalu gbọ ibi to ba ba iwadii naa de.

Awa naa yoo ṣe iwadii tiwa - Ileeṣẹ eto ẹkọ

Ileeṣẹ eto ẹkọ

Oríṣun àwòrán, @NigEducation

Ẹwẹ, ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ni Naijiria naa ti sọ pe oun yoo gbe iwadii toun dide lati mọ kulẹkulẹ ọrọ ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Boriowo Folasade, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan.

Boriowo sọ pe ileeṣẹ ọhun ti gbọ nipa bi awọn ile ẹkọ kan ṣe n yọ lara owo ti awọn akẹkọọ ya.

O fi kun pe mininisita fun eto ẹkọ, Maruf Olatunji Alausa koro oju si igbesẹ ti wọn ni awọn ile ẹkọ naa n gbe, ileeṣẹ naa yoo si gbe iwadii awọn dide lori rẹ.

O pari ọrọ rẹ pe ajọ naa ko ni yẹsẹ ninu afojusun rẹ lati ri daju pe awọn ọmọ Naijiria lanfaani sieto ẹkọ to peye, ati lati ri pe ẹnikẹni ko ko owo ti ijọba ya sọtọ fun eto ẹkọ sapo ara wọn.