Iná sọ lọ̀jà fóònù ní Ilorin, dúkìá olówo iyebíye, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fóònù jóná

Aworan die lara awọn ṣọọbu to jona
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Awọn ontaja ninu ọja foonu to wa lagbegbe Challenge, niluu Ilorin, ṣi wa ninu ibanujẹ bayii, latari ina kan to sọ lọja naa lalẹ Ọjọruu.

Ọpọlọpọ foonu tuntun ti wọn n ta pẹlu awọn eyi ti wọn n tunṣe lọwọ lo ba iṣẹlẹ ina ojiji naa lọ, gẹgẹ bi awọn tọrọ naa kan ṣe ṣalaye.

Ẹnikan to pe orukọ rẹ ni Yusuf, sọ fun BBC pe nnkan bii aago mẹsan alẹ ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin to pari yii ni ina ọhun ṣẹyọ lojiji, ninu ọkan lara awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta foonu naa.

Ki wọn too ri ohunkohun ṣe si i, ina ti jo ọpọ foonu raurau.

Alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Hasan Hakeem, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Hasan sọ pe nnkan bii aago mẹsan-alẹ kọja iṣẹju mẹfa ni wọn pe awọn lati pa ina naa.

O fi kun un pe ileeṣẹ panapana gbiyanju lati pa ina ọhun, ṣugbọn ṣọọbu mẹwaa lo jona patapata .

Adari agba pata nileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni John Olumuyiwa, ba gbogbo awọn ti ṣọọbu wọn jona kẹdun.

O ṣalaye pe ina mọnamọna lo fa ijamba yii, o si gba awọn eeyan nimọran lati maa ṣọra.