Owu Waterfalls, ibùdó afẹ́ 'tó léwu ní lílọ̀ láì mú ẹ̀ṣọ́ aláàbò dáni'

Àkọlé fídíò, Owu Waterfalls, ibùdó afẹ́ ‘tó léwu ní lílọ̀ láì mú ẹ̀ṣọ́ aláàbò dáni’
Owu Waterfalls, ibùdó afẹ́ 'tó léwu ní lílọ̀ láì mú ẹ̀ṣọ́ aláàbò dáni'

Ni ipinlẹ Kwara, ibudo igbafẹ oju ọjọ kan wa fun awọn eeyan ti wọn ba nifẹ si ayika. Omi ori apata Owu Waterfalls ni wọn n pe ibudo naa.

Omi atapata da silẹ, Owu Waterfalls yii wa lara awọn omi atapata da walẹ to ga julọ lorilẹ Afirika to si rẹwa pupọ fun oju.

Amọṣa, pẹlu gbogbo ẹwa ati ọṣọ ti Ọba oke fi ta ibudo irinajo afẹ yii lọrẹ opopona to lọ sibẹ jẹ eyi to bani ninu jẹ jọjọ. Opopona yii ti wa di panpẹ ijangbọn to n da ẹru ba ọpọlọpọ awọn to n rin in.

BBC Yoruba de ibẹ lati wo awọn ọna yii, bo ṣe ri ati iriri awọn eeyan agbegbe naa.