'Bí àwọn èèyàn bá rí mi, ọmọ gómìnà Adeleke ni wọ́n ń pè mí nítorí pé a jọra gidigidi'
Ni igbagbọ Yoruba, mejimeji ni Eleduwa da eniyan ti wọ si gbagbọ pe gbogbo eniyan to wa laye lo ni eeyan kan to jọ wọn bi ibeji.
Lara awn bẹẹ to wa lagbo gbajumọ ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke wa nitori laarin ipinlẹ rẹ ni a ti ri arakunrin kan to jọ Gomina naa bi imumu.
Kaakiri tibu toro Naijiria ni Gomina Ademọla Adeleke ti gbayi paapaajulọ fun ijo jijo rẹ.
Ọgbẹni Oluwaseyi Afonriwo jẹ ẹni ti ọpọ ti tọka si pe o jọ gomina Adeleke bi imumu.
Nigba ti ikọ BBC News Yoruba de ọdọ rẹ a rii pe ko si irọ ninu ọrọ yii, koda, ti iduro, ati iṣesi lo fi jọ Gomina ipinlẹ Ọṣun naa.
"Bí baba si ọmọ ni Gomina Ademọla Adeleke ṣe mu mi, ti wọn si n tọju mi."

Ninu ọrọ to ba BBC news Yoruba sọ, Ọgbẹni Oluwaseyi Afonriwo ṣalaye pe jijọ ti oun jọ gomina Adeleke ti mu oriire bao un o nitori pe lọwọ yii oun gan ti di onile.
O ni bi Gomina ipinlẹ Ọṣun naa ṣe fẹran orin ati lati maa jo ni oun pẹlu fẹran ijo jijo.
"Bí baba si ọmọ ni Gomina Ademọla Adeleke ṣe mu mi, ti wọn si n tọju mi.






