Ṣé lóòótọ́ ni Portable yóò ṣe ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta gẹ́gẹ́bí iléẹjọ́ ṣe pàṣẹ́?

Oríṣun àwòrán, instagram/portable
Ileẹjọ Majisireeti agba to w ani agbegbe Ifọ ni ipinlẹ Ogun ti ran gbajumọ akọrin takasufe, Habeeb Ọlalọmi Okikiọla ti ọpọ mọ si Portable lọ si ẹwọn oṣu mẹta.
Adajọ Majisireeti agba Babajide Ilo gbe idajọ naa kalẹ lori ẹsun mẹta to da lori lilu eniyan ati jiji ohun elo orin eyi ti wọn fi kan Portable niwaju ile ẹjọ naa ni oṣu kẹrin ọdun 2023. Nigba naa, wọn gba beeli akọrin naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N300, 000) ati oniduro meji nigba naa.
Ohun ti a gbọ ni pe Portable ti kọkọ Farahan niwaju ileẹjọ naa lọjọbọ to kọja, ki wọn to ju u si atimọle fun kikuna lati Farahan niwaju ile ẹjọ naa lainaani gbogbo isunsiwaju to ti de ba igbẹjọ naa.
Ṣaaju ni ọlọpaa to lewaju ikọ olupẹjọ fun ẹjọ naa, Ripẹtọ Olumide Awoleke ti fi to ile ẹjọ naa leti pe ọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun 2022 ní nnkan bii agogo mọkanla owurọ ni Portable da ẹsun naa ni Okeosa, Ilogbo lagbegbe Ifọ.
Kí ni idajọ ileẹjọ naa sọ?

Oríṣun àwòrán, portable
Gẹgẹbi iwe ipẹjọ rẹ pẹlu nọmba MIF/192C/2023 ṣe laa kalẹ pe Portable "digbo lu arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Osumosu Emmanuel Oluwafẹmi"
Bakannaa ni iwe ipẹjọrẹ tun la a kalẹ pe lọdun 2022, Portable ji awọn ohun elo orin ninu eyi ti ohun elo orin loriṣiriṣi.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Majisireeti agba Ilo sọ pe Portable jẹbi ẹsun kinni ati ikeji ti wọn fi kan an.
Adajọ naa ran Portable lọ si ẹwọn oṣu kan pẹlu anfani owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun ẹsun akọkọ; ẹwọn oṣu meji tabi anfani owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun Naira fun ẹsun keji.
Ohun ti a gbọ ni pe Portable san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira, owo itanran naa tosi gba ile rẹ lọ.















