Wo bí o ṣe lè mọ iléeṣẹ́ tó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lu CAC

Aworan idanimọ CAC

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n ri si iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ ni Naijiria, Corporate Affairs Commission (CAC), ti fun awọn ileeṣẹ ti ko ba ti i fi orukọ silẹ ni gbedeke ọsẹ mẹfa lati ṣe bẹẹ.

Atẹjade kan ti CAC fi sita lori ayelujara lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2025 lo fidi eyi mulẹ.

Ninu atẹjade CAC ni wọn ti kilọ pe ẹni to ba kuna lati forukọ ileeṣẹ rẹ silẹ yoo fi ẹwọn jura.

Gẹgẹ bi CAC ṣe wi:

" Iwa ọdaran ni labẹ ofin to de iforukọsilẹ ileeṣẹ, abala 863 ti wọn gbe kalẹ ni 2020, lati maa ṣe òwò ni Naijiria gẹgẹ bii ileeṣẹ, alajọṣe tabi pẹlu orukọ kan lai fi orukọ ileeṣẹ naa silẹ."

Wọn fi kun un pe iwa ọdaran ni lati maa lo orukọ kan to yatọ si eyi ti ileeṣẹ fi silẹ lọdọ ijọba.

Bakan naa ni wọn gba awọn ọmọ Naijiria nimọran, lati tẹle abala 729 ofin iforukọsilẹ, eyi to ni wọn gbọdọ jẹ ki orukọ idanimọ ileeṣẹ wọn han nibi ti iṣẹ tabi okoowo ọhun ti n waye.

Ẹni to ba lu ofin iforukọsilẹ yii, ijiya wa fun bi CAC ṣe wi, o si le jẹ pe ẹwọn ọdun meji ni ẹni naa yoo fi jura.

Bí o ṣe lè mọ iléeṣẹ́ tó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú CAC

Hussaini Ishaq Magaji, (SAN) Ọga agba CAC

Oríṣun àwòrán, CORPORATE AFFAIRS COMMISSION/X

Àkọlé àwòrán, Hussaini Ishaq Magaji, (SAN) Ọga agba CAC
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ki ileeṣẹ tabi okoowo too le fẹsẹ mulẹ ni Naijiria, o gbọdọ forukọ silẹ pẹlu ajọ ti a mọ si CAC.

Lati fi orukọ ileeṣẹ naa silẹ nirọrun, ileeṣẹ ọhun yoo ti wa ni ibamu pẹlu gbogbo ohun ti CAC n fẹ.

Awọn bii orukọ ileeṣẹ naa, ibi to fidi kalẹ si, awọn wo ni adari ati alajọpin rẹ, ilana wo ni wọn n gba pin owo, wọn si gbọdọ ti sanwo iforukọ silẹ to yẹ pẹlu.

Lẹyin ti CAC ba fi orukọ ileeṣẹ naa silẹ tan, wọn yoo fun un ni iwe ẹri iforukọsilẹ, eyi ti orukọ ileeṣẹ naa yoo wa nibẹ gadagba.

Yoo tun ṣalaye boya ileeṣẹ aladaani ni tabi ti ijọba.

Wọn yoo fun wọn ni nọmba iforukọsilẹ ti a mọ si 'RC Number', eyi ti yoo jẹ ti ileeṣẹ naa nikan ṣoṣo.

Iwe-ẹri naa yoo tun ni ọjọ iforukọsilẹ lori, pẹlu idanimọ oluforukọsilẹ agba ajọ naa.

Ko ma baa di pe awọn eeyan n bọ sọwọ onijibiti nibi ti wọn ti n forukọ silẹ, ajọ CAC ti ṣi oju opo apapọ kan lori ẹka ayelujara wọn, eyi to le fi han bi ileeṣẹ ba fi orukọ silẹ ni tododo.

Bi o ba fẹẹ mọ ileeṣẹ to fi orukọ silẹ, CAC sọ pe o le wo ẹka ayelujara ajọ naa nipa titẹ 'Public Search'.

Lẹyin naa ni wa a tẹ nọmba RC ileeṣẹ naa, tabi orukọ ileeṣẹ ọhun ni kikun, ati 'search' lẹyin eyi.

Bi okoowo tabi ileeṣẹ naa ba ti fi orukọ silẹ, orukọ rẹ, numbẹr RC ati adirẹsi rẹ yoo jade kedere.

Orukọ awọn oludari ati awọn alajọpin rẹ nikan ni ko ni i gbe jade.

Bí o ṣe lè fi orúkọ iléeṣẹ́ sílẹ̀ ní Naijiria

Aworan ileeṣẹ CAC

Oríṣun àwòrán, CORPORATE AFFAIRS COMMISSION/X

Ajọ CAC yii naa ni ofin fọwọ si ni Naijiria lati fi orukọ ileeṣẹ tabi okoowo silẹ, yala aladaani tabi ti ijọba, ileeṣẹ kekere tabi nla.

Gẹgẹ bo ṣe wa loju opo ayelujara CAC, ilana iforukọ ileeṣẹ silẹ ko le rara.

Ohun akọkọ naa ni fun ẹni to fẹẹ fi orukọ ileeṣẹ rẹ silẹ lati lọ si oju opo CAC, ko si tẹle awọn ilana ti wọn la kalẹ nibẹ fun un.