Àtúntò tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn alákóòṣo àti òṣìṣẹ́ 200 ní iléeṣẹ̀ ìfọporọ̀bì Naijiria, NNPCL, ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan Bashir Ojulari

Oríṣun àwòrán, NNPCL Limited/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ ifọporobi orilẹede Naijiria, NNPCL, ti yọ awọn alakooso ileeṣẹ ifọporọbi Naijiria to wa ni Warri, Port Harcourt ati Kaduna nipo.

NNPCL jawe gbele ẹ bakan naa fawọn ọga agba mii nile iṣẹ ifọporọbi ọhun, lara wọn ni Ọgbẹni Bala Wunti to jẹ adari ẹka to n ri si okowo labẹ NNPCL.

Igbimọ alaṣẹ tuntun NNPCL ti sọ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ naa to ku ọdun kan fun wọn lati fẹyin ti lẹnu iṣẹ lati fi iṣẹ silẹ bakan naa.

Bi ẹ o ba gbagbe, lọjọ keji oṣu Kẹrin yii ni Aarẹ Bola Tinubu yọ alakooṣo agba ileesẹ NNPCL, Mele Kyari, nipo to fi mọ awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ ifọporọbi naa.

Lati ọdun 2019 ni Kyari ti ṣe akoso NNPCL titi ti Tinubu fi jawe lọ gbele ẹ fun un loṣu yii.

Oṣiṣẹ NNPCL kan ti ko darukọ ara rẹ sọ fun akọroyin iwe iroyin Punch wi pe ''Aarẹ yọ awọn eeyan nipo tori wọn o ṣe daadaa to lẹnu iṣẹ wọn.

Oju kan naa ni wọn ti n yika, koda, awọn gan an wa lara iṣoro ti NNPCL n koju.

Ileeṣẹ NNPCL nilo idari ọtun, akọṣẹmọṣẹ ni gbogbo awọn ti aarẹ ṣẹṣẹ yan sipo bayii.

Gbogbo awọn eeyan lo mọ apade ati alude nnkan to n lọ lẹka ifọporọbi, wọn kii ṣe oloṣelu.

Igba akọkọ ree ti gbogbo awọn alaṣẹ NNPCL yoo jẹ akọṣẹmọṣẹ.''

Oṣiṣẹ mii naa sọ pe iyọnipo Kyari ko ni ṣe pẹlu ọjọ ori rẹ. O ni ''NNPCL kii ṣe ileeṣẹ ijọba nikan ti ẹnikan le maa dari bẹẹ.

O yẹ ki awọn akọṣẹmọsẹ ti wọn le mu idagbasoke ba ileeṣẹ maa darapọ mọ NNPCL loorekoore.

A ni lati mọ iye epo rọbi ti NNPCL n fọ, aarẹ fẹ ki a maa fọ epo bii agba 3,000,000 lojumọ nigba to ba di ọdun 2030.

Ati pe laarin akoko yii si ọdun 2027, a gbọdọ ri pe a n fọ epo agba miliọnu meji lojoojumọ lai si idaduro kankan.

Bakan naa, aarẹ fẹ ki a maa pese afẹfẹ gaasi biliọnu mẹwaa kubiiki laarin akoko yii titi di ọdun 2030.

Awọn nnkan ti aarẹ fẹ ki wọn ṣe niyii, ti o dẹ ṣe yẹ ki o ri niyii.

Kókó mẹ́fà nípa Bashir Ojulari ti Tinubu yan bíi adarí ìgbìmọ̀ alákòsóo tuntun fún àjọ NNPC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ileeṣẹ Aarẹ kede awọn adari tuntun fun ajọ naa, ti Bashir Ojulari jẹ adari wọn nigba ti Ahmadu Kida yoo jẹ alaga.

Yatọ si awọn meji yii, Tinubu tun yan awọn aṣoju kaakiri ẹkun to wa ni Naijiria ti yoo maa ba awọn eeyan naa ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọmọ igbimọ.

Awọn ọmọ igbimọ naa ni Bello Rabiu, Yusuf Usman, ati Babs Omotowa ti gbogbo wọn wa lati iha ariwa.

Aarẹ tun kede orukọ Austin Avuru, David Ige, Henry Obih ati Lydia Shehu Jafiya, ti wọn wa lati iha ila oorun ati iwọ oorun.

Lati akoko yii lọ, Aminu Ahmed ni yoo maa ṣoju ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi ni Naijiiria.

Ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ni awọn eeyan naa bẹrẹ iṣẹ ni ọọfisi ti Aarẹ yan wọn si.

Lati ọdun 2023 ni Aarẹ Tinubu ti n gbe awọn igbesẹ ti yoo mu NNPC pa owo wọle siwaju si fun Naijiria.

Lọdun to kọja, idokowo to le ni biliọnu mẹtadinlogun dọla ni NNPC ṣe.

Ileesẹ Aarẹ ni afojusun oun ni lati maa fọ miliọnu meji agba epo loojọ titi ọdun 2027 ati miliọnu mẹta agba epo loojọ ti yoo ba fi di ọdun 2030.

Koko mẹfa pataki nipa aseyọri Ojulari lẹka epo rọbi

  • Ojulari ti lo ọdun to le ni mẹrinlelogoji lẹka epo rọbi ati afẹfẹ gaasi, lara awọn agbọn to si ti sisẹ ni akoso ati akojọ awọn ohun elo ati irinsẹ fun ipese epo rọbi.
  • Ojulari ni imọ nipa idokowo lẹka epo rọbi, wiwa epo rọbi, mimu idagbasoke ba ẹka epo rọbi akoso ipese epo rọbi ati awọn ẹka miran
  • Iyansipo rẹ bii alakoso agba fun ileesẹ NNPC ni yoo fun ileesẹ naa ni anfaani lati se amusẹ ipese ẹgbẹrun meji agba epo rọbi lojumọ ati sise agbega eto ọrọ aje Naijiria
  • Ojulari lo jẹ Oludari agba fun ẹka ipese epo rọbi ati wiwa rẹ labẹ ileesẹ ifọpo Shell ti wọn n pe ni SNEPCo laarin ọdun 2015 si 2021
  • Nigba ti Ojulari n sisẹ nileesẹ ifọpo Shell, oun lo n sakoso awọn ohun eelo to wọn n lo labẹ omi lati wa epo rọbi, ti wọn si n wa agba epo to le ni ẹgbẹrun lọna okoolelọọdunrun ni ojumọ, ti owona wọn si n to biliọnu kan dọla
  • Labẹ akoso Ojulari, aseyọri lo ba ileesẹ ifọpo Shell to fi mọ alekun ida ogun ninu ọgọrun ipese epo rọbi, mimu adinku bii ida ọgbọn ba owona wọn nidi akoso ati mimu adinku ida ogoji ba owo ti wọn n na lati sisẹ
  • Wọn fun Ojulari ni ami ẹyẹ Bonga Asset award lọdun 2016, to si tun lo awọn ọgbọn atinuda rẹ nidi fifi ọwọ si eto adehun to nii se pẹlu isẹ agbase nidi pinpin eroja epo rọbi ati yiyanju aawọ pẹlu OML-118, eyi to mu ki wọn dawọle isẹ agabse fun idagbasoke ti owo rẹ to biliọnu mẹfa si mẹjọ Dọla.
  • Lara awọn ipenija to wa niwaju ileesẹ NNPC ti Ojulari yoo koju ni iwa biba ọpa epo jẹ, jiji epo rọbi wa ati ipe araalu pe ki wọn siju idokowo Naijiria kuro ni ẹka epo rọbi nikan.