Ta a ni Aisha Achimugu, oníṣòwò ńlá tí EFCC mú fún ẹ̀sùn jìbìtì ?

Oríṣun àwòrán, Aisha Ashimugu/ Facebook
Nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹrin 2025 ni ajọ EFCC to n gbogun ti ajẹbanu lorilẹ ede yii, nawọ gan obinrin oniṣowo nla nni, Aisha Sulaiman Achimugu.
Papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, niluu Abuja, ni wọn ti mu un.
Ṣaaju ni EFCC ti kede pe awọn n wa Achimugu lori ẹsun jibiti, fifi iṣẹ ire boju lati kowo jọ (Money laundering).
Bi Achimugu, Alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ nla to n ri si ọrọ epo ati nnkan amuṣagbara ṣe n balẹ si Naijiria lati London laaarọ oni ni EFCC mu un.
Ọkan lara awọn lọọya rẹ, Chikaosolu Ojukwu, (SAN), fidi ẹ mulẹ pe EFCC ti mu Achimugu.
O ni bi wọn ṣe mu un naa lo ti bẹrẹ si i yan oujẹ lodi, lati fi ẹhonu rẹ han.
Ṣugbọn ta a ni Aisha Acimugu, ki lo da oun ati EFCC ti wọn fi n wa a ki wọn too gbe e janto bayii?
Aisha Achimugu
Onileeṣẹ nla, olokoowo ati ẹni to n ri si igbaye-gbadun pẹlu alaafia ọmọniyan ni ọpọ eeyan mọ Aisha Sulaiman Achimugu si.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe wi, iwadii EFCC fi han pe apo ikowosi 136 ni Aisha Achimugu ni kaakiri awọn ile ifowopamọ mẹwaa.
Wọn ni orukọ ileeṣẹ rẹ ati orukọ adani lo fi n lo awọn akanti ọhun.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta 2025 ni EFCC kede pe awọn n wa Aisha Achimugu.
Ẹsun igbimọpọ lu jibiti, fifi iṣẹ to ba ofin mu boju labẹ ohun to lodi sofin, ati nini awọn dukia to lodi sofin ni wọn fi kan an nigba naa.
Lọjọ kẹta oṣu Kẹrin, Achimugu pe ẹjọ ti ko ni i jẹ ki EFCC ati awọn agbofinro yooku le mu un tabi ti i mọle.
Lọjọ Aje, Adajọ Inyang Ekwo, paṣẹ nile ẹjọ giga Abuja, pe ki Achimugu foju han ni kootu lọjọ Iṣẹgun, ko si tun ṣe bẹẹ l'Ọjọruu ọsẹ yii.
Ṣaaju ni Achimugu ti sọ pe ki I ṣe pe oun k fẹẹ yọju si EFCC, o ni itọju ilera toun lọọ gba loke okun ni ko jẹ
Awọn ẹsun mi-in ti EFCC tun fi kan oniṣowo nla yii ni pe awọn owo nla n wọnu apo ikowosi rẹ.
Owo kan to to N8.71 billion ni wọn lo wọ akanti Achimugu, to si ni awọn alabadowopọ oun lo fi ranṣẹ sibẹ.
O ni wọn ni koun fowo naa ṣowo epo rọbi ni.
Owo ẹyin ati magomago ni ajọ EFCC pe e.
Eyi atawọn mi-in ni wọn yoo maa gbe yẹwo nile ẹjọ .














