Kí ni òfin sọ nípa títàbùkù owó ilẹ̀ òkèèrè tó mú E-Money wọ gbaga EFCC?

Emeka Okonkwo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí E-Money

Oríṣun àwòrán, IAM_EMONEY/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti tú gbajúmọ̀ oníṣòwò, Emeka Okonkwo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí E-Money, sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n mu fẹ̀sùn pé ó ṣe owó náírà àti owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́.

Ọjọ́rú ni E-Money gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ EFCC, tí wọ́n sì ní ó máa fojú ba ilé ẹjọ́ láìpẹ́.

Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC News Pidgin lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun pé E-Money wà ní àhámọ́ àwọn.

Ẹ̀sùn pé ó ṣe owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́ ni gbajúmọ̀ náà ń kojú, bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn-án pé ó ná owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́ èyí tí wọ́n ní ó lòdì sí òfin Foreign Exchange Act.

Ibi ètò ìnáwó kan tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n fẹ̀sùn kàn-án pó ó ti náwó náà lọ́nà àìtọ́.

Ní agbègbè Omole ní Eko ni wọ́n ti nawọ́ gán E-Money, tí wọ́n sì gbe lọ sí Abuja fún ìwádìí àti láti fojú rẹ̀ ba ilé ẹjọ́.

E-Money ló ń kojú ẹ̀sùn ṣíṣe owó náírà kúmọkùmọ èyí tí EFCC ń kojú oro sí pàápàá fáwọn tó jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká.

Láìpẹ́ yìí ni ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Eko fi olórin tàkasúfèé kan, Terry Alexander Ejeh tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Terry Apala sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi fẹ́sùn pé ó ṣe owó náírà kúmọkùmọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

EFCC wọ́ Terry Apala lọ iwájú Adájọ́ Akintayo Aluko fẹ́sùn ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ níbi ayẹyẹ kan tó wáyé ní Madison Place, tó wà ní Oniru, ìpínlẹ̀ Eko.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, agbẹjọ́rò EFCC bèèrè fún ọjọ́ tí ìgbẹ́jọ́ yóò wáyé àti pé kí wọ́n fi afurasí náà sí àhámọ́ títí di ìgbà náà.

Ní oṣù Kẹrin ọdún 2024, gbajúmọ̀ akọ tó máa ń múra bíi obìnrin, Idris Okuneye tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky kó sí àhámọ́ EFCC fẹ́sùn pé ó ṣe owọ náírà bí kò ṣe tọ́ níbi ayẹyẹ kan.

Bobrisky ní òun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun tí Adájọ́ Abimbola Awogboro tí ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ sì dájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún-un.

Lọ́dún tó kọjá bákan náà ni ilé ẹjọ́ kan gba ìtúsílẹ̀ Pascal Okechukwu tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Cubana Chief Priest lẹ́yìn tí EFCC mu fún ẹ̀sùn ṣíṣe owó náírà lọ́nà tí kò tọ̀nà.

Cubana Chief Priest ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí EFCC fi kan òun, tí ilé ẹjọ́ sì gba béèlì rẹ̀ pẹ̀lú mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà pẹ̀lú onídùúró méjì.

Kí ni òfin sọ nípa títàbùkù owó ilẹ̀ òkèèrè?

Abala kọkàndínlọ́gbọ̀n (29)(1)(a) ìwé òfin Foreign Exchange Act sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá lu jìbìtì, ṣe ayédèrú tàbí ṣe owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́ jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣẹ ẹ̀ṣẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn náà ni ó ṣeéṣe kó lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún tàbí kí ó san ìlọ́po márùn-ún owó tó fi ṣẹ̀ṣẹ̀ náà.

Tó bá sì jẹ́ pé iléeṣẹ́ kan ló ṣẹ̀, iléeẹ́ náà máa san ìlọ́po mẹ́wàá owó ọ̀hún.

Bákan náà ni abala Kọkànlélógún òfin Nigerian CBN Act ní ẹ̀ṣẹ̀ ni láti tàbùkù owó náírà. Ẹnikẹ́ni tó bá tàbùkù owó náírà ṣeéṣe kó lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà tàbí ko san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún àádọ́ta náírà.

Lára àwọn ọ̀nà tí èèyàn lè gbà tàbùkù náírà ni níná owó lójú agbo, kíkọ nǹkan sára owó, títẹ owó náírà mọ́lẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

E-Money, ọ̀dọ́mọdé olówó wọ gbaga EFCC

Emeka Okonkwo Daniel ti ọpọ mọ si E-money

Oríṣun àwòrán, E-Money/x

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹede Naijiria, EFCC ti fi panpẹ ofin mu gbajumọ ọdọmọde olowo ni, Emeka Okonkwo Daniel ti ọpọ eeyan mọ si E-Money.

Ohun ti ọpọ iroyin n sọ ni pe gbigbe ti EFCC fi ofin gbe E-Money ni ẹsun nina owo dọla loju agbo ode ijo kan laipẹ yii.

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Dele Oyewọle fi idi iroyin yii mulẹ fun BBC.

O ni alẹ ọjọ Aje ni wọn gbe gbajumọ oniṣowo naa.

Ta ni E-Money?

Olóyè Emeka Okonkwo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí E-Money jẹ́ oníṣòwò, olùdókoòwò àti ẹlẹ́yinjú àánú.

Ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejì, ọdún 1981 ni wọ́n bi ní agbègbè Ajegunle, Eko.

Agbo eré ìdárayá ni ó ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ayé rẹ̀. Òun ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Five Star Music tó jẹ́ iléeṣẹ́ orin.

Bákan náà ló tún ní iléeṣẹ́ Five Star Oil, tó jẹ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo.

E-Money ní ìyàwó, Juliet Okonkwo, tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́ta.