Kí nídìí tí ìjọba àpapọ̀ fi fẹ́ wọ́gilé ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ òkèèrè fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ètò BEA?

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba Nàìjíríà ti kéde pé àwọn fẹ́ fòpin sí àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèèrè, tí wọ́n fi máa ń rán àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti lọ kàwé ní orílẹ̀ èdè mìíràn lọ́fẹ̀ẹ́ ìyẹn Bilateral Education Agreement, BEA.

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, Tunji Alausa ló kéde ìpinnu ìjọba náà lásìkò tó gbàlejò ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Alausa wòye pé ètò náà kò rẹsẹ̀ walẹ̀ àti pé níṣe ló dàbí tí èèyàn bá ń ná owó aráàlù ṣòfò.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ètò yìí nílẹ̀ òkèèrè ń fẹ̀sùn kan ìjọba Nàìjíríà pé wọn kò ṣe ẹ̀tọ́ tó yẹ fún àwọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.

Kí ni Bilateral Education Agreement, BEA?

Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lójú òpó ayélujára iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, BEA jẹ́ àdéhùn láàárín Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ òkèèrè láti pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní ipele ètò ẹ̀kọ́ gíga yàlá ẹ̀kọ́ onípò kìíní, onípò kejì tàbí ọ̀mọ̀wé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà.

Èyí túmọ̀ sí pé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá wà ní abẹ́ àǹfàní yìí kò ní sanwó fún ètò ẹ̀kọ́ nílẹ̀ òkèèrè ìjọba ni yóò ṣe àmójútó rẹ̀.

Orílẹ̀ èdè tí akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ bá wà ni yóò máa san owó ilé ẹ̀kọ́ àti owó ilé nígbà tí ìjọba Nàìjíríà yóò máa $500 lóṣù gẹ́gẹ́ bí owó oúnjẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Bákan náà ni wọ́n tún lẹ́tọ̀ọ́ sí $250 gẹ́gẹ́ bí owó aṣọ lọ́dún, $200 fún ètò ìlera lọ́dún, àtàwọn àǹfàní míì tí ìjọba ń pèsè fún wọn.

Lára àwọn orílẹ̀èdè tí Nàìjíríà ti bá tọwọ́bọ àdéhùn láti máa pèsè irú ètò yìí ni China, Russia, Algeria, Serbia, Morocco, Egypt àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Láìpẹ́ yìí ni ìjọba kéde pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà lábẹ́ ètò yìí ni àwọn tis an gbogbo ẹ̀tọ́ tó yẹ títí di ìparí ọdún 2024 fún àti pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn máasan gbèsè tó kù tí wọ́n jẹ wọ́n ní kòpẹ́ kòpẹ́.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ti wá kéde báyìí pé àwọn máa fòpin sí ètò náà àmọ́ tí wọ́n gbogbo àwọn tó ti wà lórí ètò yìí ni àwọn máa ṣe ẹ̀tọ́ lórí wọn títí tí wọ́n fi máa parí ẹ̀kọ́ wọn.

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ sọ pé kò ní sí ìgbànìyàn fún ètò náà mọ́ láti ọdún 2025 yìí mọ́.

Kí ló dé tí ìjọba fòpin sí BEA?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alausa ṣàlàyé pé àwọn máa da owó tí àwọn ń ná fún ètò náà sórí àwọn ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní Nàìjíríà dípò kíkó irú owó bẹ́ẹ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.

Ó ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lọ kọ́ nílẹ̀ òkèèrè ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Nàìjíríà le pèsè.

"Nígbà tí mo gba ipò lọ́dún 2024, wọ́n ní kí n buwọ́lu N650m fún akẹ́kọ̀ọ́ ọgọ́ta tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Morocco lábẹ́ ètò BEA, mo kọ̀ láti buwọ́lù ú."

Mínisítà náà sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló lọ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Gẹ̀ẹ́sì, psychology, sociology nílẹ̀ òkèèrè léyìí tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga Nàìjíríà ló ń kọ́ àwọn iṣẹ́ náà.

"Mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan – àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ kọ́ ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Algeria tó jẹ́ pé èdè Faranse ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Kò bá làákàyè mu rárá.

"N9bn ni a gbèrò láti ná lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 1,200 tó wà nílẹ̀ òkèèrè lọ́dún 2025 nìkan. Kò sì sí àtìlẹyìn kankan tí à ń ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nílé.

"Gbogbo iṣẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí sì ń kọ́ nílẹ̀ òkèèrè láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ti wa náà ń ṣe."

Bákan náà ló fi kun pé kò sí àmójútó tó péye fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kúrò ní Nàìjíríà tán.

Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo àwọn tọ wà lórí ètò náà lọ́wọ́ ni àwọn máa ṣe àtìlẹyìn fún tí wọ́n fi máa parí ẹ̀kọ́ wọn àmọ́ àwọn kò ní gba àwọn mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọdún 2025.