Àwọn òṣìṣẹ́ bínú sí ìjọba Naijiria láyàájọ́ ọjọ́ òṣìṣẹ́

Aworan awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Gbagede Eagle Square, l'Abuja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbogbo ọjọ kin-in-ni oṣu Karun-un ọdun ni ayajọ awọn oṣiṣẹ lagbaaye, eyi lo fa a ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ orilẹede Naijiria naa ṣe darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn kari aye lati sami ayẹyẹ naa.

Ṣugbọn idunnu ko si lọkan awọn oṣiṣẹ yii.

Wọn fi ibanujẹ ọkan wọn han sijọba ni gbagede Eagle Square, to wa niluu Abuja, nibi ti ayẹyẹ naa ti waye.

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, (NLC) lorilẹede Naijiria, Joe Ajaero ati Festus Osifo(TUC), koro oju si ijọba Naijiria, pẹlu alaye pe ko yẹ ki oṣiṣẹ tun di atọrọjẹ lẹyin iṣẹ ti wọn n ṣe.

Wọn ni ṣugbọn o ṣe ni laanu pe ohun ti oṣiṣẹ Naijiria n koju ree.

Ọdún ìdárò là ń se, kì í ṣe ọdún àwọn òṣìṣẹ́-Ajaero

Aworan ẹgbẹ awọn nọọsi nibi eto naa

Ninu ọrọ Joe Ajaero, Aarẹ NLC naa sọ pe ki i ṣe ajọyọ ọdun oṣiṣẹ lawọn n ṣe rara.

Ajaero sọ pe idaro ara awọn fun wahala ati idaamu tawọn oṣiṣẹ Naijiria n koju lawọn tori rẹ peju si gbagede.

O ni bo ṣe jẹ pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lo ja fun eto ominira to, sibẹ, awọn oṣiṣẹ naa lo tun n jẹ ìyà to pọ ju.

Kọmureedi Ajaero sọ pe ẹkunwo tijọba ṣe nipa owo oṣu, ti wọn ni wọn yoo maa san ẹgbẹ̀rún laadọrin (70,000) ko to rara.

Ajaero ṣalaye pe owo naa ko too ra irẹsi apo kan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ijọba to n fi ara ni araalu naa ko ni i wa bẹẹ titi lae.

Bakan naa ni Ajaero fi kun un pe awọn oṣiṣẹ ti iya n jẹ ko ni i dakẹ.

O ni awọn yoo maa pariwo inira tijọba n mu ba oṣiṣẹ ni.

Kí ni ẹgbẹ́ oṣiṣẹ ń bèèrè ?

Awọn oṣiṣẹ miran nibi eto naa

Lara awọn alakalẹ ẹtọ ti ẹgbẹ oṣiṣẹ kede lọjọ naa pe awọn n fẹ lati ọdọ ijọba ni:

  • Kijọba apapọ ati tipinlẹ ṣeto ti yoo dẹkun òsì.
  • Ki atunṣe de ba owó oṣu awọn oṣiṣẹ
  • Kíjọba ṣàlàyé ohun to n jẹ sisan owo-ori níbi owó oṣù
  • Yiyọ aba owo ori to wa niwaju ile igbimọ asofin kúrò.

Ajaero tesiwaju pe asiko niyi fawọn ẹgbẹ́ oṣiṣẹ lati ja fun ẹtọ wọn.

O rọ wọn lati ma ṣe sọ ireti nu, labẹẹ bo ti wu ko ri.

Kaka bẹẹ, o ni ki wọn ṣe ara wọn loṣuṣu ọwọ lati ja ajaṣẹgun ni.

Àyájọ́ òṣìṣẹ́ May 1 ní Nàìjíríà, òṣìṣẹ́ ń lọgun ìlú le, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń bèèrè fún ẹ̀kúnwó owó oṣù

Aworan awọn olori apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, NLC/X

Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria n beere fun ẹkunwo owo oṣu bi wọn ti n ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ lonii ọjọ kinni oṣu Karun un ọdun 2025 yii.

Akori ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ ti ọdun yii ni wọn pe ni ''igbayegbadun oṣiṣẹ pẹlu bi ilu ṣe le koko.''

Ayajọ ọjọ oṣiṣẹ ti ọdun yii waye lasiko ti ọwọngogo gbode ti ọrọ aje orilẹede Naijiria si n ṣojojo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti yọ owo iranwọ ori epo kuro ni ọwọngogo ti gbode ti atijẹ atimu ṣi le koko fun araalu.

Eyi lo jẹ kawọn oṣiṣẹ beere fun alekun owo oṣu tori owo ti wọn n gba ko to gbọ bukata mọ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti buwọlu N70,000 gẹgẹ bi owo osu oṣiṣẹ to kere julọ, ajọ aladaani kan ti orukọ rẹ n jẹ BudgIT sọ pe ipinlẹ mẹtadinlogun pere lo ti bẹrẹ si ni san owo oṣu to kere julọ naa bayii.

Ajọ naa ni ọgunlọgọ ileeṣẹ aladaani ni ko tii bẹrẹ si ni san owo oṣu naa titi ti asiko yii.

Awọn ẹka ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria sọ pe ọwọngogo gbode lo jẹ ko ṣe pataki lati ṣe alekun owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni kiakia.

Alaga ẹgbẹ oṣiṣe ti ẹka ipinlẹ Oyo, Kọmureedi Kayode Martins, sọ pe iṣoro ọwọngogo ti araalu n koju ko yọ awọn oṣiṣẹ naa silẹ.

Kọmureedi Martins ni awọn oṣiṣẹ lo fara kaasa awọn eto ijọba to jẹ ki nnkan le koko julọ, o ni ọwọngogo to gbode ko jẹ kawọn oṣiṣẹ le gbe igbe aye to rọrun.

Alaga NLC l'Oyo ni owo oṣu tawọn osiṣẹ n gba lasiko ijọba Tinubu ko to lati ra nnkan ti wọn nilo mọ.

O ni owo ounjẹ ati owo ọkọ lọ sibi iṣẹ ti pọju, ohun lo si n gbe owo awọn oṣiṣẹ lọ ju.

Kọmureedi Funmi Sessi ti i ṣe alaga ẹgbẹ NLC nipinlẹ Eko naa kọminu lori ọwọngogo nnkan to gbode ati bi ijọba ko ṣe wa ojutuu si ọrọ naa.

O ni owo ile, owo ọkọ, owo ile ẹkọ fawọn ọmọ ati owo ounjẹ ti gara fun ọpọlọpọ oṣiṣẹ ni Naijiria.

Kọmureedi Sessi o ṣeni laanu pe ijọba ko ri nnkankan ṣe si bi owo nnkan se n lọ soke ti ko si walẹ rara.

Alaga ẹgbẹ oṣiṣe TUC nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Akeem Lasisi, ko si nnkan koriya fawọn osiṣẹ lati ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣisẹ lọdun yii pẹlu bi ilu ṣe ri.

''Awọn oṣiṣẹ ni igi lẹyin ọgba ọrọ aje Naijiria''

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Godswill Akpabio, gboṣuba rabandẹ fawọn oṣiṣẹ fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe fun idagbasoke ọrọ aje orilẹede Naijiria.

Akpabio ni awọn oṣiṣẹ Naijiria jara mọ iṣẹ bẹẹ ni wọn kii sii kaarẹ lẹnu iṣẹ nigba kankan.

Aarẹ ile aṣofin agba sọ ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oludamọran rẹ lori ilukoro ati eto iroyin, Eseme Eyiboh, pe ''awa aṣofin mọ riri iṣẹ ribiribi tawọn oṣiṣẹ Naijiria n ṣe fun idagbasoke ọrọ aje orilẹede wa.

Mo yin wọn fun ifarada wọn pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe ri lọwọ yii pẹlu ọrọ aje Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ipenija lo n koju ọrọ aje wa, ẹyin oṣiṣẹ si ni igi lẹyin ọgba ọrọ aje Naijiria.

Isẹ ti ẹ n ṣe pataki fun idagbasoke ati ilọsiwaju orilẹede Naijiria.''

Iṣẹ nla lawọn oṣiṣẹ n ṣe fun ọrọ aje Naijiria – Oluremi Tinubu

Ninu ọrọ tiẹ, aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu, ki awọn oṣiṣẹ fun atilẹyin ti wọn n ṣe fun ọrọ aje Naijiria.

''Kaakiri orilẹede Naijiria, bo ya oṣiṣẹ ijọba ni o tabi ti aladaani, awọn oṣiṣẹ ni opomulero idagbasoke ọrọ aje orilẹede Naijiria.

Mo ki gbogbo oṣiṣẹ lọkunrin lobinrin ti wọn n ṣiṣẹ lojoojumọ fun idagbasoke ọrọ aje Naijiria, mo si ki wọn ku ayajọ ọjọ oṣiṣẹ ti ọdun yii,'' Tinubu lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sita.

Aya aarẹ ni ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ ti ọdun yii n ran ni leti iṣepataki fifun gbogbo eeyan lanfaani lati ṣiṣẹ lai ṣegbe lẹyin ẹnikan.