Wọ́n rí òkú ọlọ́pàá mẹta tó di àwátì nínú odò lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà

Keamogetswe Buys ati Cebekhulu Linda

Oríṣun àwòrán, South Africa Police Service

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede South Africa ti bẹrẹ iwadii lẹyin ti wọn ri oku ọlọpaa mẹta to ti kọkọ di awati fun ọjọ mẹfa, ninu odo.

Ọjọru to kọja ni wọn ri Boipelo Senoge, ẹni ogun ọdun, Cebekhulu Linda, ẹni ọdun mẹrinlelogun , ati Keamogetswe Buys, ẹni ọgbọn ọdun, kẹhin lasiko ti wọn kuro ni ileepo kan nitosi ilu Johannesburg.

Ibẹrẹ ọsẹ yii ni awọn omuwẹ ri oku wọn ninu odo Hennops, eyi to wa ni bi aadọrin kilomita si Johannesburg. Bakan naa ni wọn ri ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu rẹ ninu odo ọhun lọjọbọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ sọ pe awọn n ṣe iwadii pe o ṣee ṣe ki awọn kan ti gbaṣakoso ọkọ wọn. Ṣugbọn nigba to n sọrọ l'Ọjọbọ, ọga ọlọpaa sọ fun awọn akọroyin pe, "riri ti wọn ri wọn, jọ ijamba ọkọ" bo tilẹ jẹ pe, iwadii imọ ijinlẹ yoo ṣi waye lori oku ati ọkọ naa.

Awọn ọlọpaa mẹtẹẹta - ti gbogbo wọn jẹ kọnsitebu - n rinrinajo ninu ọkọ VW Polo, ti awọ rẹ jẹ funfun, ki wọn to o di awati, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ.

Lati igba naa si ni ẹrọ to n tọpinpin ọkọ wọn, ati awọn foonu wọn, ti wa ni pipa.

Ọga Ọlọpaa i orilẹede naa, Fannie Masemola, sọ pe tọsa-toru ni ikọ to wa wọn fi rin kaakiri agbegbe Gauteng, Free State ati Limpopo, fun ọpọlọpọ ọjọ - ko to o di pe wọn ri awọn ẹya ọkọ "to jọ ti VW Polo".

Lẹyin naa ni wọn ri ọkọ akẹru kan Renault Kangoo, nitosi eti odo Hennops, ki wọn o tun to o ri oku eeyan meji.

Ọjọbọ ni wọn fa ọkọ ayọkẹlẹ VW Polo jade ninu odo.

Ilu Free State ni awọn ọlọpaa mẹtẹẹta ti n rinrinajo lọ si Limpopo, nigba ti wọn di awati.

Yatọ si oku awọn kọnsitebu mẹtẹẹta, awọn omuwẹ tun ri oku oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa kan ti wọn ko ti i darukọ rẹ. Oun lo wa ọkọ akẹru Renault naa, gẹgẹ bi Gen Masemola, ṣe sọ.

He added that the fifth body was decomposed and had not yet been identified. O fikun un pe, oku ẹni karun un ti wọn ri, ti jẹra, ti wọn ko si ti i le sọ pato ẹni to jẹ.

Kọnsitebu Boipelo Senoge wa lara awọn ọlọpaa mẹta, ti wọn ri oku wọn ninu odo

Oríṣun àwòrán, South Africa Police Service

Àkọlé àwòrán, Kọnsitebu Boipelo Senoge wa lara awọn ọlọpaa mẹta, ti wọn ri oku wọn ninu odo

Ṣaaju ki wọn o to ri oku awọn ọlọpaa naa, ni awọn eniyan orilẹede South Africa ti n gbadura fun riri wọn lori ayelujara.

Lẹyin ti wọn ri oku wọn, ni awọn ẹbi ati ọrẹ wọn korajọ si eti odo Hennops, pẹlu abẹla lọwọ wọn.