Wo bí ayẹyẹ ìgbadé Owa Obokun tuntun, Adesuyi Haastrup, yóò ṣe wáyé n'Ilesa

Oríṣun àwòrán, THE POINTING
Aafin Owa Obokun Adimula ilẹ Ijesa ti kede bi eto ayẹyẹ igbade ọba tuntun, Owa Clement Adesuyi Haastrup, Ajimoko III, yoo ṣe waye nilẹ Ijesa, ipinlẹ Osun.
Ọba Adesuyi to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Osun ni yoo jẹ Owa kọkandinlaadọta (49th) ilẹ Ijesa.
Eyi n waye lẹyin ipapoda Owa Gabriel Adekunle Aromolaran II, to waja lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2024.
Atẹjade ti Oloye Shola Oshunkeye, Alaga igbimọ to n ri si ikede lori iwuyẹ naa fi sita, ṣalaye pe ọjọ mẹwaa gbako ni ọlọkan-o-jọkan eto igbade Owa tuntun yoo fi waye.
Báyìí ni ètò gbogbo yóò ṣe lọ
Eto yiyan Owa tuntun, Adesuyi Haastrup, Ajimoko III yoo bẹrẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un ọdun 2025.
Akanṣe irun Jimọ kiki ni wọn yoo fi bẹrẹ, ni mọṣalaaṣi apapọ ilu ilesa. aago kan ọsan ni wọn ni eyi yoo bẹrẹ.
Ọjọ Abamẹta, ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un ni ayẹyẹ nilana ibilẹ yoo waye ni gbọngan Obokungbusi, bẹrẹ lati aago mẹwaa owurọ titi di aago mẹrin irọlẹ.
Wọn yoo ṣe alẹ Iṣẹṣe laafin pẹlu, eyi yoo bẹrẹ laago mẹsan-an alẹ.
Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un ni wọn ya sọtọ fun Kabiyesi lati ṣabẹwo sawọn agbegbe ilẹ Ijesa, laaarin aago mẹwaa owruọ si mẹrin irọlẹ.
Ogunjọ oṣu Karun-un ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun ni ere idaraya yoo waye, wọn yoo sare ije, bẹrẹ lati aago meje owurọ.
Kete ti aago mẹwaa aarọ ba lu lọjọ naa, ifigagbaga lori bọọlu afẹsẹgba yoo waye, wọn yoo si fun awọn to ba yege ni ami ẹyẹ ni Ilesa Grammar School.
Ọjọruu, ọjọ kọkanlelogun ni wọn ya sọtọ fun lilọ sile awọn ọmọ alai-ni-obi kaakiri Ilesa, ti wọn yoo si fi ẹbun ta wọn lọrẹ .
Aago mẹwaa owurọ ni wọn ni eyi yoo bẹrẹ.
Ere idaraya yoo tun waye lọjọ kejilelogun, pẹlu eyi ti a mọ si Golf, bẹrẹ lati aago mẹjọ owurọ.
Eto riro awon akẹkọọ lagbara pẹlu ẹkọ ọfẹ yoo waye pẹlu.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un gan-an ni ọjọ igbade
Bi atejade ṣe wi, aago mẹwaa owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un ọdun 2025 ni Owa Clement Adesuyi Haastrup, Ajimoko III, yoo gba ade laafin gẹgẹ bii olorii gbogbo ọba ilẹ Ijesa.
To ba di aago kan ọsan, wẹjẹ-wẹmu yoo waye ni Ilesa Grammar School.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un 2025 ni Owa tuntun yoo lọ ṣe idupẹ ni ṣọọṣi Methodist, Otapete, n'Ilesa.
Aago mẹwaa owurọ ni wọn pe eto to kadi gbogbo ẹ nilẹ ọhun.
Ta a ni Adesuyi Haastrup?

Owa Adesuyi Haastrup ni igbakeji gomina ipinlẹ Osun nigba kan, Oloogbe Isiaka Adeleke, laarin ọdun 1992 si 1993.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 1948 ni wọn bi Haastrup ni idile Ajimoko ti ilẹ Ijesa.
O kẹkọọ ni Eko Boys High School laarin ọdun 1963 si 1967, ko too tẹsiwaju ni Federal School of Sciences, ipinlẹ Eko, laarin ọdun 1968 si 1969.
Lẹyin naa lo lọ kẹkọọ ni Fasiti Howard, to wa niluu Washington D.C., nilẹ Amẹrika.
Olokoowo ati olowo nla taye n pe ni billionaire lawọn eeyan mọ Owa Adesuyi Haastrup si lawujọ.
Ṣaaju ni awọn idile oye kan ti n fi apa janu pe, awọn afọbajẹ ko tẹle ilana to yẹ lori iyansipo Haastrup.
Ṣugbọn ni ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2024, Gomina Ademola Adeleke, gbe ọpa aṣẹ fun un ni gbọngan Obokungbusi, ilu Ilesa, ipinlẹ Osun.














