A ò gbà pé ìdájọ́ òdodo ti wáyé lórí ikú Bamise tí awakọ̀ BRT pa - Ẹbí Bamise Ayanwola fárígá lẹ́yìn ìdájọ́

Oríṣun àwòrán, facebook/bamishe ayanlowo/bbc
Lẹyin ti ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ si agbegbe Tafawa Balewa Square, TBS, nipinlẹ Eko ti dajọ iku fun Andrew Nice Ominikoron, awakọ BRT ti wọn lo pa oloogbe Bamishe Ayanwola, to si tun ba a lo pọ, BBC ba awọn ẹbi oloogbe Bamishe ati awọn ẹgbẹ to n ja fun idajọ ododo nipa iku rẹ sọrọ.
Awọn ẹgbọn oloogbe meji, ọkunrin ati obinrin, ṣalaye pe awọn kan lo ran Andrew Nice lọwọ lati pa Bamishe.
Wọn ni awọn ko gba pe idajọ ododo ni kootu ṣe yii, pẹlu bi awọn ti wọn jọ siṣẹ ibi naa ko ṣe ti i di mimu.
''Bi wọn ko ba foju awọn ti wọn jọ pa Bamishe han, a ko ti i gba pe idajọ ododo waye rara''
Bẹẹ ni awọn eeyan naa wi.
Ilé-ẹjọ́ dájọ́ ikú fún awakọ̀ BRT tó pa Bamishe Ayanwola l'Eko
Ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ si agbegbe Tafawa Balewa Square, TBS, nipinlẹ Eko ti dajọ iku fun Andrew Nice, awakọ BRT ti wọn lo pa oloogbe Bamishe Ayanwola, to si tun ba a lo pọ.
Ọjọ Ẹti, ọjọ keji oṣu Karun-un ọdun 2025 ni idajọ ọhun waye, lẹyin ọdun mẹta ti Bamishe ti jade laye.
Yatọ si idajọ iku, adajọ tun sọ pe ki Andrew Nice ṣe ẹwọn gbere fun ẹsun ifipabanilopọ.
Yatọ si Bamishe ti a gbọ pe awakọ naa fipa ba lo pọ, ile-ẹjọ sọ pe o tun fipa ba awọn obinrin meji miran lo pọ pẹlu.
Mary Jane Odezulu ati Dokita Oyinyechi ni wọn pe orukọ awọn obinrin naa.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Oríṣun àwòrán, Bamise ayanwola
Loṣu Kẹta ọdun 2022 ni wọn kọkọ gbe Ominikoron ẹni ọdun mẹtadinlaadota lọ ile ẹjọ lori ẹsun onikoko marun un to da lori ifipabanilopọ, igbimọpọ lati ṣeka, ati ipaniyan.
Ijọba ipinle Eko fẹsun kan awakọ BRT naa pe o gbimọ pọ pẹlu awọn eeyan kan lati fipa ba Bamise ọmọ ọdun mejilelogun lopọ ati lati ṣeku pa a lojọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2022.
Gẹgẹ bi igbimọ olupẹjọ ti ṣalaye, ni nnkan bi ago meje alẹ ni wọn fipa ba Bamise to n ṣiṣẹ aranṣọ lopọ ti wọn si tun ṣeku pa a lopopona Lekki-Ajah si afara Carter Bridge.
Igbimọ olupẹjọ ni lẹyin ti awakọ BRT naa atawọn ti wọn jọ gbimọ pọ pa Bamise ṣe iṣẹ laabi wọn tan ni wọn ju u sita lati oju ferese ọkọ to n lọ eyi to jẹ ko farapa yanayana.
Amọ, Ominikoron duro lori ẹsẹ rẹ wi pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.
O ni oun ko mọ ohunkohun nipa ifipabanilopọ ati iṣekupa Bamise to jẹ aranṣọ.
Ominikoron ṣalaye pe awọn ero ọkunrin mẹta toun gbe lẹyin toun ti ṣiwọ iṣẹ ni wọn ṣe ikọlu si Bamise ti wọn si tun ju u sita lati oju ferese ọkọ naa.
'Àwọn tó pa Bamise nínú BRT ba ojú ara àbúrò mi jẹ́ yánkan-yànkan'
Ẹgbọn ọdọbirin ti wọn ni awakọ BRT ṣekupa l'Eko, iyẹn Oluwabamise Ayanwola, ti sọ fun ile ẹjọ to n gbọ ẹsun naa pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ lasiko ti awọn ọlọpaa yoo fi ṣawari oku rẹ.
Ibatan rẹ ọhun, Abegunde Ayanwola lo sọ ọrọ naa lasiko to wa jẹri niwaju ile ẹjọ tako awakọ BRT ti wọn ni o pa ọdọbirin naa, Andrew Nice Ominikoron.
Andrew Nice yii ni wọn fẹsun kan pe o ba oloogbe naa lopọ pẹlu ipa, to tun gba ẹmi rẹ lẹyin naa.
O tun n koju ẹsun ibalopọ ero ọkọ mii, iyẹn Maryjane Odezelu.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2022 yii ni Bamise kuro nile lati ṣabẹwo si ọkan lara awọn ẹgbọn rẹ, amọ ko de ibi to n lọ, eyii lo mu ki wọn bẹrẹ si ni wa a.
Ọkan lara awọn ọrẹ Bamise lo ṣalaye fun awọn mọlẹbi rẹ pe o n ba oun sọrọ loju opo WhatsApp pe oun wọ inu ọkọ ero BTR, amọ pe ẹru n ba oun ninu ọkọ ero naa nitori awọn nnkan ti oun fura si lẹyin ti gbogbo awọn ero ọkọ naa ti sọto si ku oun nikan sinu rẹ pẹlu awakọ.
Abegunde ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye pe Bamise ati ọrẹ rẹ ọhun fi ohun ranṣẹ si ara wọn lori WhatsApp, eredi ree ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lọ ṣe ọfintoto bi oloogbe naa ṣe rin ni ileeṣẹ to n bojuto BRT l'Eko.
O fi kun pe ileeṣẹ BRT beere aṣẹ lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn to fun awọn laṣẹ lati wo aworan ori CCTV inu BRT naa.
Gẹgẹ bii ohun ti Abegunde sọ, awọn ọlọpaa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa, eyi to mu ki wọn kọ lẹta si ọọfisi ileeṣẹ to n ṣakoso BRT l'Eko, LAMATA ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun.
O ni lẹyin oniruuru igbiyanju ni wọn ri oku aburo oun nile igbokusi kan lọjọ keje, oṣu Kẹta, lẹyin ti ẹnikan dari awọn si agọ ọlọpaa to wa ni Ebute Ero.
Nigba ti agbẹjọro afurasi bere lọwọ ẹgbọn Bamise ohun to n gbiyanju lati sọ nigba to sọ pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ.
Pẹlu omije loju, o ni "'Virgin' ni ọmọ naa, ti awọn ọkunrin bii meji si mẹta si ba a lopọ, ṣe ẹ fẹ ki n maa ṣalaye bi oju ara rẹ sẹ ri ni? Rara o! Mi o le ṣalaye."












