Èmi ni Ọba Fuji, kí Kwam 1 má pe ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́ – Kollington Ayinla

Kollington Ayinla ati K1 D Ultimate

Oríṣun àwòrán, @fujiopera

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja olorin Fuji, General Kollington Ayinla, ti kede pe oun gan ni Ọba Fuji ni Naijiria ati loke okun.

Ayinla lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Agbaletu TV nibi to ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa akitiyan rẹ ninu Fuji ni Naijiria.

Ọrọ naa lo jẹyọ latari ọrọ to n lọ nipa ibaṣepọ rẹ pẹlu Wasiu Ayinde Marshal, ti ọpọ mọ si K1 De Ultimate.

Nigba to n ṣalaye nipa eredi ti ko fi yọju sibi eto isinku iya to bi Wasiu Ayinde, o ni gbogbo igbiyanju oun lati lati kan si K1 lo ja si pabo.

O ni "Mo pe e lọpọ igba amọ o kọ lati gbe aago ipe mi, koda mo pe e lọjọ ọdun tuntun, ko dahun, lẹyin naa ni mo fi silẹ."

Ayinla tun mẹnuba ipo ti K1 wa ninu ilẹ Ijebu nibi to ti ṣalaye pe jijẹ oloye ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu ipo rẹ ninu agbo Fuji.

O tẹsiwaju pe "To ba jẹ pe oun ni olori gbogbo awọn ọmọọba, ilu rẹ niyẹn; iyẹn ko sọ pe oun ni Ọba Fuji. Ṣe o fẹ sọ ara rẹ di Ọlọrun ni?

"Ti a ba n sọrọ nipa Fuji, awọn eeyan mọ ẹni to bẹrẹ rẹ, ti a ba n sọrọ Fuji, orukọ mi ni wọn maa n kọkọ da.

"Ko kan mi nipa ohun ti awọn eeyan ba n pe ara wọn, oke tente ni mo wa ninu agbo Fuji."

Nigba to n ṣalaye nipa orisun Fuji, Ayinla sọ pe "Fuji ti wa ki n to bẹrẹ si n kọ orin, ṣugbọn awa ni a fun ni ẹmi lati wa laaye.

"Mo jiya gidi nitori Fuji amọ mi o sọ ireti nu, emi ati Sikiru ni a bẹrẹ Fuji ni ibẹrẹpẹpẹ."

Ayinla sọ pee lootọ ni K1 ti ṣe ọpọ aṣeyọri ninu iṣẹ orin Fuji amọ ko tumọ si pe ko maa pe ara rẹ ni nnkan ti ko jẹ.

O ni "Ọpọ aṣeyọri ni K1 ti ṣe, o si mọ ọpọ awọn eeyan pataki ṣugbọn ko tumọ si pe ko maa pe ara rẹ ni olori, emi ni olori ninu agbo Fuji, ootọ to wa nibẹ niyẹn."