Darandaran tó fi mààlúù jẹko l'Ondo gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ Majisreeti kan nilu Akure, ipinlẹ Ondo, ti ran darandaran kan, Dan-Bello, ni ẹwọn ọdun mẹwaa fun fifi maaluu jẹ oko oloko ati biba ere oko jẹ.
Adajọ Damilola Sekoni to gbe idajọ naa kalẹ, ṣalaye pe ẹri foju han lọpọlọpọ, pe darandaran naa jẹbi.
Ire oko to to miliọnu lọna aadọta naira (50m) ni wọn lo bajẹ.
Ẹsun mẹta mi-in ti i ṣe igbimọpọ ṣiṣẹ ibi, wiwọ oko lọna aitọ ati dida omi alaafia ilu ru tun ni Dan-Bello jẹjọ rẹ.
Lori gbogbo ẹsun naa ni wọn si ti ri i pe o jẹbi.
Ori ilẹ kan to jẹ ti National Palm Produce Association of Nigeria (NPPAN), to wa loju ọna Ago Panu–Ute Road, nijọba ibilẹ Owo ni wọn lo ti ba awọn ọ̀pẹ to ṣẹṣẹ n dagba jẹ, pẹlu eso watermelon ti wọn gbin sori saarẹ ilẹ meji (Two hectares).
Ṣaaju ni agbefọba P.O. Nwafor, ti sọ fun kootu pe olujẹjọ fi ẹran jẹko naa lai gba aṣẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023.
O ni lori ilẹ ti ijọba ipinlẹ Ondo ko faaye silẹ pe ki wọn ko maaluu wọ ni Dan-Bello tun ko ẹran rẹ wọ.
Eyi tako ofin sinsin nnkan ọsin ati bi ẹranko yoo ṣe maa ri ounjẹ jẹ nipinlẹ Ondo, eyi ti wọn gbe kalẹ lọdun-un 2021.
''Wọn tun pada sọ ina soko naa lẹyin ti wọn ko maaluu wọbẹ''
Agbefọba Nwafor tẹsiwaju, pe Dan-Bello nikan kọ lo fi ẹran jẹko naa nigba ti wọn kọkọ wọbẹ, o tun ku ẹnikan.
O ni ṣugbọn ẹni naa sa lọ.
Ọjọ keji iṣẹlẹ naa lo ni awọn gbọ pe eyi to sa lọ naa tun pada wa si oko yii pẹlu awọn mẹfa mi-in, wọn si sọ ina si oko naa.
Nibi tina ọhun ti n jo ni ọkada kan to wa nibẹ naa ti jona bo ṣe wi.
Ọkan lara awọn ẹṣọ oko naa to jẹrii tako o ni kootu, ṣalaye bo ṣe ri Dan-Bello mu, nigba ti ẹnikeji rẹ sa lọ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Damilola Sekoni, ju Dan-Bello si ẹwọn ọdun mẹrin fun ẹsun akọkọ, ko fi aaye owo itanran silẹ fun un.
Ẹwọn ọdun meji lo ju u si fun ẹsun keji, o fun ni aaye owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta.
O ju u si ẹwọn ọdun kan fun ẹsun kẹta ati ikẹrin.
Ẹwọn ọdun meji mi-in lo ran an fun ẹsun karun-un, bẹẹ ni aaye owo itanran ko yọ.
Aṣepọ ni gbogbo ẹwọn naa bi Adajọ Ṣekoni ṣe paṣẹ.
Ṣugbọn bi olujẹjọ ba le san miliọnu meji naira fun olupẹjọ, Adajọ Sekoni sọ pe yoo gba ominira.
O ni o ṣe pataki fun awọn darandaran lati maa tẹle ofin to de fifi ẹran jẹko nipinlẹ naa, lati le kapa ija awọn agbẹ ati darandaran l'Ondo.














