Ṣé lóòótọ́ ni CBEX ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Nigerian stores/X
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin tun gbode kan wi pe oriko idokowo owo ilẹ okere lori ayelujara ti ọpọ eeyan n fura wi pe o fi ara pẹ atẹ sogundogoji, CBEX ti pade de lẹyin ọsẹ meloo kan ti wọn fa gbogbo owo awọn oludokowo kuro ninu apo asunwọn wọn.
BBC Yoruba kan si awọn eeyan kan ti wọn si n ṣe CBEX labẹ aṣọ, gbogbo wọn ni wọn si fi idi rẹ mulẹ wi pe looto ni idokoowo ori ayelujara naa ti pade de.
Alaye ti wọn ṣe fun akọrọyin wa ni pe CBEX sọ fun awọn oludokowo wọn wi pe awọn ko mọ bi owo ṣe poora ninu awọn apo asunwọn naa, ṣugbọn awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati riidaju wi pe gbogbo oludokowo to padanu owo lo ri owo wọn gba pada.
Eyii lo mu ki awọn alakoso CBEX sọ fun gbogbo ẹni ti owo rẹ n bẹ labẹ ẹgbẹrun kan Dollar, pe wọn gbọdọ san ọgọrun Dollar ki wọn le ri owo wọn gba pada, awọn ti owo ti wọn ju ẹgbẹrun kan Dollar lọ ni lati san okere tan, igba Dollar ki owo naa le pada si apo asunwọn wọn.
Gbogbo awọn to san owo yii ni wọn ti ri gbogbo owo wọn to poora gba pada sinu apo asunwọn wọn, ṣugbọn o di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun yii ki wọn to le gba ida aadọta jade ninu owo naa. Ọjọ kẹdọgbọn oṣu kẹjọ ni wọn o ni anfani lati gba eleyii to ṣẹku ninu owo wọn.
Awọn alakoso CBEX tun sọ fun awọn oludokowo wọn wi pe bẹrẹ lati ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwaa ọdun yii, gbogbo awọn to n ṣe karakata lori atẹ idokowo naa yoo maa ni anfani lati gba ida ọgbọn jade ninu owo ti wọn ba pa ni oṣooṣu.
Yatọ si awọn eto ti wọn gbe kalẹ yii, CBEX tun fun awọn oludokowo wọn ni anfani lati ṣi apo asunwọn tuntun ki wọn le maa ṣe karakata ki wọn si maa gba owo jade saaju ileri ti wọn ṣe fun oṣu kẹfa. Owo to kere ju ti wọn fi le ṣi apo asunwọn tuntun jẹ ọọdunrun Dollar.
Awọn ti a ṣe ifọrọwẹrọ fun ṣe alaye siwaju sii pe gbogbo awọn ti wọn ṣi apo asunwọn tuntun yii ni wọn ti n ri owo gba jade.
Awọn ere ajẹmọnu, iyẹn 'Bonus' ti CBEX n fun awọn apo asunwọn tuntun ṣee gba jade lẹsẹkẹsẹ. Alaye ti wọn tun ṣe fun akọroyin wa ni wi pe gbogbo ẹni to ti fi ẹnu tabuku atẹ karakata naa ni yoo yi ọrọ wọn pada nigba ti awọn ba bẹrẹ sini gba owo jade lọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun yii.
Lati igba ti iroyin awọn owo to poora ninu apo asunwọn CBEX ti lu sita ni ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti bẹrẹ iwadii, bakan naa sini wọn ti kede awọn afurasi kan ti ajọ naa n wa nitori owo awọn awọn eeyan to poora, gẹgẹ bi wọn ṣe fi n da awọn to padanu owo wọn loju wi pe owo naa yoo jẹ dida pada.
Awọn to n ṣe CBEX tun sọ fun akọroyin wa labẹ aṣọ wi pe iṣẹ iwadii ti ajọ EFCC n ṣe lo mu ki awọn alakoso atẹ idokowo naa sun awọn owo ti wọn fẹ san pada di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun yii.















