Lẹ́yìn ọdún mẹta, erò ọkọ̀ ojú irin pàdé ẹni to jì i gbe ní mọ́ṣáláṣí

Oríṣun àwòrán, Vanguard News
Ẹni to ṣu lo gbagbe, ẹni to ko imi ọhun ko ni i gbagbe rara ni ti iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ ni mọṣalaṣi kan nipinlẹ Kaduna.
Ajinigbe ati ẹni to ji gbe lo foju kan ara wọn lẹyin ọdun mẹta.
Ọkunrin kan, Kọmureedi M.B Muhammad, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ero ọkọ oju irin reluwee tawọn ajinigbe ji gbe loṣu Kẹta ọdun 2022, lo pade ọkan lara awọn to ji wọn gbe nigba naa.
Bi wọn ṣe ji wọn gbe nigba naa ni wọn ko wọn si ahamọ fun igba pipẹ, wọn si fiya ti ko ṣee gbagbe jẹ wọn titi ki wọn too fi wọn silẹ lẹyin owo itusilẹ gọbọi.
Wọn pa awọn mi-in ninu awọn ero ọkọ naa pẹlu.
Gẹgẹ bi Muhammad ṣe ṣalaye, o ni laipẹ yii loun ya mọṣalaṣi Shema, nitosi Ibudokọ Bakin Ruwa, ni Kaduna, lati kirun.
O ni afi boun ṣe ri ọkan ninu awọn ajinigbe naa torukọ rẹ n jẹ Abubakar, toun naa n kirun ninu mọṣalaṣi kan naa.
Dajudaju, ajinigbe ko da Muhammad mọ̀ mọ́, ṣugbọn ẹni to ji gbe ranti oju rẹ daadaa lai ṣiyemeji.
Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fojú kan ara wọn?

Oríṣun àwòrán, Bolanle Cole
Alaye Muhammad bo ṣe kọ ọ soju opo ayelujara rẹ ni pe,
"Lalẹ ana nigba ti mo kirun Isha'i tan ni Mọṣalaṣi Shema, mo ri ọkan lara awọn to ji wa gbe ninu ọkọ reluwee AK-9 tawọn ajinigbe kọlu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2022, nigba ta a n lọ si Kaduna lati Abuja.
"Abubakar lorukọ ẹ. O sọ fun mi pe oun ti yipada, oun o ṣe ijinigbe ati janduku mọ. Ọkada lo n gun bayii to fi n ṣiṣẹ.
"Lẹyin ti mo ba a sọrọ fun igba pipẹ, o jẹ ko ye mi pe awọn kan ti ku ninu awọn to ji wa gbe, bẹẹ lawọn mi-in ṣi n tẹsiwaju ninu iwa igbesunmọmi .
"Ni kẹyin ṣaa, mo sọ fun un pe mo ti dari ji i atawọn yooku rẹ, mo si fun un ni itọrẹ aanu nitori ipo ti mo ba a. Oluwa gbogbo aye, fi wa mọna ko o si fi wọn mọna pẹlu."
Bẹẹ ni Kọmureedi Muhammad ṣalaye.
Tẹ o ba gbagbe, irọlẹ ọjọ Aje, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ́n oṣù kẹta ọdun 2022 ikọlu ati ijinigbe naa waye ni márosẹ̀ Abuja sí Kaduna.
Awọn agbébọn kọlu ọkọ oju irin naa ti wọn si ji ọ̀pọ̀lọpọ̀ eeyan wọgbo lọ.
Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni awọn ajinigbe yii kọlù ọkọ to ko bii ẹgbẹẹrun kan eeyan.
Awọn o ṣoju mi kòró sọ pé ọkọ̀ ojú irin naa yẹ kúrò lójú ọnà rẹ̀ nígbà tí nǹkan dún gbàmù lára rẹ̀ lasiko irin ajo naa.














