Mo bù sẹ́kún nígbà tí mo rí fọ́nrán àwọn èèyàn kan tó ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí mi ò lọ́kọ - Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja oṣerebinrin, Funke Akindele ti sọrọ nipa awọn ilakọja to la kọja lori ayelujara nipa bi ko ṣe ni ade ori.
Akindele nigba to n ba Chude Jideonwo sọrọ, ṣalaye pe bi o ti jẹ pe ọpọ ri oun gẹgẹ bii akinkanju obinrin, ọpọ nnkan loun n la kọja, paapa lori ayelujara.
Iya Ibeji ni lẹyin iku iya rẹ, ijakulẹ rẹ ninu oṣelu, ọpọ yẹyẹ ti awọn eeyan kan fi ṣe paapa lori igbeyawo rẹ ana, eyi to ko si ọpọ ironu, to si nilo lati rọ ri akọsẹmọsẹ.
O ni oun wo fọnran kan lori ayelujara nibi ti awọn eeyan kan ti n fi ṣe yẹyẹ nitori oun ko ni ade ori, ti eyi si gba omije loju rẹ.
O tẹsiwaju pe kete ti oun bẹrẹ si ni ma ba akọsẹmọsẹ sọrọ, igba ọtun de ba oun.
Funkẹ Akindele sọ pe oun mọ pe biba akọsẹmọsẹ sọrọ nipa ipo ironu eeyan ṣe koko ṣugbọn oun kọ lati ṣe eyi nitori aifẹ ki gbogbo agbaye mọ nipa ohun gbogbo ti oun n la kọja.
"Mo n ku sinu pẹlu idakẹ mi nitori mo n ṣe ọkan akin. Ni gbogbo igba ti mo ba fi ọkan akin mi ran sita, wọn ma n ja mi kulẹ, ni ile, lati ọwọ mọlẹbi, nibi iṣẹ, ni awujọ.
"Mo jẹ eeyan lile. Mo jẹ ọmọ akin. Mo ma n ri ọpọ iwọsi nipa mi lori ayelujara ṣugbọn mo ma n mu mọr, o de asiko kan, mo fẹ ya mi ni were.
Agba oṣere naa tun mẹnuba gbogbo ohun to la kọja pẹlu iku iya rẹ ninu eyi to ni ọpọ ọrọ iwọsi lawọn eeyan fi ṣọwọ si oun.
"O ni fọnran kan t imo wo nibi ti awọn eeyan kan ti n fi mi ṣe yẹyẹ nitori n ko ni ọkọ. Awọn obinrin yii n jo, ti wọn si n fi mi ṣe yẹyẹ. Mo subu, mo sukun. Mo wa sọ fun ara mi pe mo ni lati ba eeyan sọrọ. N ko le tẹsiwaju bayii."
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ọdun 2022 ni igbeyawo, Funke Akindele ati ọkọ rẹ, JJC Skills tuka.
Ọkọ Funke Akindele lo kede loju ọpọ Instagram rẹ pe awọn mejeeji ko si papọ mọ.
Ogbeni Bello salaye siwaju pe lati nkan bii odun meji seyin ni igbeyawo yii ti n ni wahala.
Atri pe oun ti sa gbogbo agbara oun lati yanju isoro naa sugbon o ju agbara ori oun lo bayii.
Ati peoun ni lati ko kuro nile leyin ti osere Funke Akindele fi dandna le e lsou meta seyin.
O ni awon kan jo wa si ibi eto ami eye AMVCA ni.
Bakan naa ni Bello to je Baba Ibeji Funke Akindele salaye pe oun se ikede yii fun araye ki won le mọ̀ pe onikaluku ti pin gaari rẹ́.
O ni awon yoo si tesiwaju lati yanju ọrọ awon Ibeji ati pinpin awon ohun ini ati okowo ti won jọ ni papọ.
Ogbeni Abdul Bello tun ni oun nigbagbo pe gbogbo re yoo yanju ni ọna kan tabi ikeji laipẹ.















