Wo ìgbésẹ̀ tí o le è gbé láti mọ̀ bóyá ojúlówó ni nọ̀ńbà NIN rẹ àti ànfàní lílo rẹ̀

Kaadi idamọ NIN

Oríṣun àwòrán, National Identity Management Commission

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti buwọlu idasilẹ oju opo kan ti yoo mu ko rọrun lati se ayẹwo boya ojulowo ni kaadi idanimọ NIN awọn ọmọ Naijiria eyi ti wọn pe ni NINAuth.

Aarẹ Bola Tinubu ti tun pa laṣẹ lilo nọmba NIN yii ni awọn ileeṣẹ ijọba, ẹka ijọba ati awọn ẹkun ijọba miiran, in ibamu pẹlu ofin ilana ajọ NIMC fun araalu lati mu idanmọ rọnu.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Kayode Adegoke fisita, eyi to ni idasilẹ oju opo ayẹwo ojulowo kaadi idamọ NIN naa yoo pese aabo fun awọn iroyin nipa araalu, ti ọpọ ẹka ijọba yoo si jẹ anfani rẹ.

"Ara erongba ijọba Aarẹ Bola Tinubu ni lati bo iroyin nipa araalu.

"Pẹlu NINAuth, o nilo awọn iwe kankan. Mu lọ sibikibi, fi han, ko si ni anfani si awọn iwe to ba nilo."

Bi o se le lo oju opo NINAuth fun ayẹwo ojulowo kaadi idamọ NIN rẹ

Adegoke rọ awọn ọmọ Naijiria lati kan si oju opo ayelujara Google Play Store ati Apple IOS App Store fun lilo NIN tuntun yii.

Gẹgẹ bii Adegoke ṣe ṣalaye, NINAuth pese ọpọ aabo fun awọn iroyin nipa to nilo aabo, ti ẹnikẹni ko si le ni anfani si.

To ba fẹ appu yii, wa kọkọ gba appu naa si ori foonu rẹ, o si ya aworan QR code pẹlu appu naa lori foonu rẹ, eyi ni yoo fa aṣopọ pẹlu appu pẹlu iroyin to wa ninu NIN rẹ tẹlẹ.

Bakan naa lo lẹ Shared Code lori appu naa lati mu ibaṣepọ naa danmọran

NINAuth tun faye gba iforukọsilẹ ojukoroju, eyi ti ọpọ awọn ileeṣẹ si le mu lo.

Adegoke tẹsiwaju pe NINAuth yoo fun ọpọ araalu ni anfani si awọn ẹka ijọba ati awọn nnkan mii bii ifọrukọ silẹ siimu, irinajo, iwe irina; owo ori sisan ati awọn nnkan mii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post