Fídíò rèé nípa bí wọn ṣe máa ń yan Póòpù tuntun
Oni, ọjọ keje oṣu Karun-un ọdun 2025 ni eto nipa bi wọn yoo ṣe yan poopu tuntun yoo bẹrẹ.
Ipade ti wọn maa n ṣe lati yan olori ijọ Aguda tuntun naa lo n waye lẹyin isin Novemdiales, eyi ti wọn ṣe lati tọrọ isinmi ayeraye fun Poopu Francis to di oloogbe.
Ipade to fẹ ẹ waye yii ni 267 iru rẹ latigba ti wọn ti n yan poopu.
Awọn agbaagba ijọ Aguda, Kadina, ti wọn peju pese silu Rome, eyi ti wọn to ọgọsan-an (180), ni wọn fi ẹnu ko laaarọ ọjọ Aje, pe ki eto naa bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun.
Ipade ti wọn yoo ti yan olori tuntun ọhun yoo waye ni Sistine Chapel, eyi ti awọn alejo ko ni i le wọbẹ lawọn ọjọ ti eto naa ba n lọ lọwọ.

Kí ni wọ́n máa ń ṣe níbi ètò ìdáńkọ́kọ́ náà?
Ipade awọn agba Alufaa to fẹẹ yan olori tuntun naa maa n bẹrẹ pẹlu isin idakẹjẹẹ ti awọn olori ijọ Aguda to fẹẹ dibo naa yoo wa. (Mass Pro Eligendo Romano Pontifice).
To ba di ọwọ ọsan, awọn alufaa to fẹẹ dibo yoo tọ lọwọọwọ lọ si Sistine Chapel, nibi ti wọn yoo ti bẹrẹ eto nipa yiyan olori tuntun.
Bi wọn ba to wọle tan, alufaa kọọkan yoo bura, gẹgẹ bo ṣe wa loju ewe kẹtalelaadọta (53),iwe ti a mọ si Universi Dominici Gregis.
Lati ara ibura yii, wọn fi ara wọn jin niyẹn lati fi otitọ inu tẹle ohun gbogbo to rọ mọ ijọ Aguda.
Bakan naa ni wọn yoo ṣeleri, pe awọn ko ni i tu aṣiri to rọ mọ yiyan olori tuntun ninu ijọ Katoliiki.
Wọn yoo si ṣeleri pe awọn ko ni i fi aaye silẹ fun ohunkohun lati ita lati nipa lori idibo ọhun.
Nigba naa ni olori eto naa yoo kede pe ẹni ti ki I ba a ṣe ara eto naa ko jade kuro ninu agọ naa kia.
Olori to n dari eto funra rẹ nikan ati ẹni ti yoo ṣe abala keji ni yoo ṣẹku.
Lẹyin ẹ ni wọn ka adura ni ibamu pẹlu Ordo Sacrorum Rituum Conclavis.
Adari eto yoo beere pe ṣe wọn ṣetan lati tẹsiwaju ninu idibo naa, tabi wọn ni nnkan kan ti wọn fẹẹ sọ lori idibo yii.
Ni gbogbo igba ti idibo ba n lọ lọwọ, awọn to n kopa nibẹ ko gbọdọ ba ẹnikẹni sọrọ nita nipa foonu tabi lẹta.
Wọn ko gbọdọ ka iwe iroyin, gbọ radio tabi tẹlifiṣan ati bẹẹ bẹẹ lọ. Afi to ba jẹ nnkan pajawiri ti ko si ọgbọn ti wọn le da si i.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìbò mélòó ni wọ́n nílò láti dìbò yan póòpù?
Ki wọn too le dibo yan poopu tuntun, ida meji awọn oludibo gbọdọ jẹ awọn to fẹ ẹnikan nipo naa.
Bi apapọ onka awọn oludibo ko ba ṣee pin si ọna mẹta, wọn yoo nilo ibo ẹnikan si i.
Bi ibo didi ba bẹrẹ ni ọsan ọjọ akọkọ, ẹẹkan yẹn naa ni wọn yoo dibo.
Awọn ọjọ yooku, wọn yoo dibo lẹẹmeji laaarọ, ẹẹmeji lọsan-an.
Lẹyin ti wọn ba ti ka awọn ibo naa tan, wọn yoo jo awọn iwe rẹ nina.
Bi ibo naa ko ba yanju, eefin dudu yoo maa jade lati oke ile ijọsin Sistine Chapel.
Ṣugbọn bi wọn ba ti yan poopu, eefin funfun ni yoo maa jade lati oke naa.
Bi ẹnu awọn ondibo ko ba ko lẹyin ọjọ mẹta idibo, wọn yoo fi aaye ọjọ kan silẹ lati gba adura, ba ara wọn sọrọ, olori yoo si fi iwaasu ranpẹ bọ wọn.
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní kété tí wọ́n bá yan póòpù tuntun?
Kete ti awọn agbaagba ba ti yan poopu tuntun, ẹni to kere ju ninu wọn yoo pe Akọwe ileewe awọn olori alufaa ati agba ẹka Sistine Chapel.
Nigba naa ni Alufaa agba pata yoo sọrọ lorukọ awọn ondibo, yoo beere lọwọ poopu tuntun pe: "Ṣe o gba lati di olori pata?"
Bi poopu naa ba ti da a lohun, yoo tun beere pe: "Ki lo fẹ ka maa pe ọ?"
Awọn akọwe meji yoo ti wa nitosi, wọn yoo duro bii ẹlẹrii, wọn yoo si kọwe to tọka si pe poopu naa gba lati di olori ijọ Aguda, ati orukọ to fẹ ki wọn maa pe oun.
Lati igba naa lọ, poopu tuntun naa ti ni agbara ati aṣẹ lori ijọ Aguda kari aye. Nigba naa si ni ipade awọn alufaa to dibo yoo ti pin.
Awọn alufaa naa yoo waa bu ọla fun poopu tuntun, wọn yoo ṣeleri lati tẹle ọrọ rẹ, wọn yoo si fọpẹ f'Oluwa.
Olori to dari eto yoo kede poopu tuntun pẹlu ẹsẹ ọrọ to gbajumọ ti wọn maa n lo, eyi ti i ṣe: "Annuntio vobis gaudium magnum; Habemus Papam."
Itumọ eyi ni pe, "mo kede pẹlu ayọ, a ti ni poopu tuntun"
Lẹyin eyi ni poopu tuntun yoo sure lati St. Peter's Basilica.
Eto to kadi ẹ nilẹ ni ki poopu tuntun gba iṣakoso Archbasilica of St. John Lateran.















