"Lẹ́yìn tí Ajínigbé gba N14m owó ìtúsílẹ̀, àpò ìrẹsì, adìẹ méjìlá tí wọn dín gbẹ, ohun mímu 24, káàdì ìpè N10,000, wọ́n tún ń bèèrè N70m míì"

Awọn ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ajinigbe to ji awọn ero ọkọ meje gbe ni abule Ẹlẹyin lopopona Isanlu Isin nigba ti wọn n bọ lati ilu Abuja lọ si ilu Ọffa ni ipinlẹ Kwara, lati bii ọsẹ mẹta sẹyin, ko tii fi wọn silẹ.

Nigba ti BBC Yoruba kan si meji ninu awọn mọlẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa, wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn lati beere fun owo itusilẹ fun awọn mọlẹbi wọn.

Lasiko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, arabinrin Gold to jẹ ẹbi ọkan lara awọn ti wọn ji gbe naa fidiẹ mulẹ pe, awọn ti san gbogbo ohun ti awọn ajinigbe naa beere fun wọn.

O fikun pe, awọn ẹbi ti kọkọ san mílíọ̀nù mẹrinla naira fawọn ajinigbe naa amọ se ni wọn faake kọri lati tu awọn eeyan wọn silẹ.

" Lẹyin ti a san N14m ati ọpọ ẹru tan, awọn ajinigbe tun n beere N70m miran"

Arabinrin Gold ni " Lẹyin ti a san milliọnu mẹrinla Naira tan, dipo ki wọn tu awọn eeyan mejeeje silẹ, se ni awn ajinigbe yii tun ni dandan, ka lọ wa owo miran si wa.

Lọtẹ yii, milliọnu lọna aadọrin Naira ni wọn tun n beere pe ka lọ wa, ki awọn to tu awọn eeyan naa silẹ.

Koda, yatọ si miliọnu mẹrinla Naira, awọn ajinigbe naa tun ti gba apo irẹsi kan ati kaadi ipe lori ẹrọ ibanisọrọ olow iyebiye.

Amọ kaka ki wọn yọnda ẹwọn mi ti wọn ji gbe, se ni wọn tún n beere fun owo idoola ẹmi miran."

Arabinrin Gold salaye siwaju si pe oun n gburo ẹgbọn oun to wa ni akata awọn ajinigbe naa, se ni wọn si n na lọpọ igba, ti wọn si n fi iya orisirisi jẹ ẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe oni Ọjọbọ lo di ọjọ kejidinlogun ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe.

Gold salaye pe oun maa n ba ẹgbọn oun sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, koda, ni ana Ọjọru, awọn ajinigbe naa tun pe oun.

"Lẹyin N14m, awọn ajinigbe tun beere apo irẹsi kan, adiẹ mejila ti a din gbẹ, ohun mimu aladun ike mejila, Mọ́ọ̀tí mejila, kaadi ipe GLO ati MTN to jẹ N10,000"

Bakan naa, nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, Alhaji Saheed toun naa jẹ ọkan lara ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa, rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ile asofin ipinlẹ naa lati ran wọn lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

"Awọn ajinigbe beere mílíọ̀nù mẹrinla naira owo itusilẹ, ti a si ti gbe lọ fun wọn.

Bẹẹ ni wọn tun beere adiyẹ ibilẹ mejila, pe ki awọn din adiyẹ naa, ko gbe daadaa, lai yọ egungun kankan kuro lara wọn.

Bakan naa, wọn tun gba ọra ohun mimu aladun ẹlẹrindodo kan to jẹ ike mejila, ọra ohun mimu Mọọti kan, iwe ipe lori foonu to jẹ ẹgbẹrun marun ₦5000 tii se tillese ibanisọrọ Glo.

Wọn si tun beere fun kaadi ipe to jẹ ẹgbẹrun marun ₦5000 miran to jẹ tillesẹ ibanisọrọ MTN."

"Ilu Omu-Aran ni a n gbe awọn ẹru ati owo lọ fawọn ajinigbe, a haaya eemeji ti a nsan N400,000 fun, ti wọn n ba wa gbe eru naa lọ"

Alhaji Saheed salaye siwaju si pe, gbogbo ohun ti awọn ajinigbe naae bere, mi awọn ti gbe lọ.

"Ilu Omu-Aran ni a ti maa n lọ gbe awọn ẹru yii fun wọn, koda, a tun haaya eemeji to n ba wa gbe awọn ohun ti ajinigbe beere lọ.

Ẹgbẹrun lọna irinwo naira, ₦400,000, si la n san fun awọn eeyan ti a haaya yii.

Sugbon iyalẹnu lo jẹ pe, lẹyin gbogbo nnkan wọnyii, awọn ajinigbe naa tun ne beere fun aadọrin mílíọ̀nù naira miran.

Wọn ni ki a san mílíọ̀nù mẹwa naira lori ikọọkan eeyan mejeeje ji wọn gbe, ti apapọ owo naa si jẹ miliọnu lọna aadọrin Naira.

A wa na rọ ijọba ati awọn ajọ eleto abo lati ran wa lọwọ nitori a lọ yá miliọnu mẹrinla Naira ti a ko fun ajinigbe lakọkọ ni"

" A ti fi isẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti, sibẹ wọn ò ti ri awọn ti wọn ji gbe ọhun gba pada"

Alhaji Saheed salaye siwaju si pe, ọkan gbogbo awọn ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa ko balẹ lori iṣẹlẹ naa.

O ni awọn ti fi isẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti, sibẹ wọn ò ti ri awọn ti wọn ji gbe ọhun gba pada.

Saheed ni laipẹ yii ni wọn ji awọn eeyan kan ninu ijọba gbe lopopona kan naa , ọjọ kẹta ni wọn yọnda wọn.