Ṣé lóòótọ́ ni Nnamdi Kanu pàṣẹ kí wọn máà pa àwọn ọlọ́pàá, tún lérí láti kọlu ìpínlẹ̀ Eko?

Ọjọruu, ọjọ kẹfa oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni igbẹjọ tun waye nile-ẹjọ giga ilu Abuja, lori ẹjọ ti Nnamdi Kanu, olori ẹgbẹ Indigenous People of Biafra (IPOB) n jẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ẹjọ igbesunmọmi ati awọn ẹsun mi-in ni ijọba apapọ Naijiria fi kan Nnamdi Kanu.
Bi igbẹjọ naa ṣe bẹrẹ, agbefọba pe ẹlẹrii keji, ẹni to pe orukọ ara rẹ ni BBB (Ki i ṣe orukọ rẹ gan-an).
Ẹlẹrii yii jẹ oṣiṣẹ DSS. Ọkunrin naa fi awọn ẹri to n kede ibi ti Kanu ti n fun awọn kan laṣẹ lati ba Naijiria ja, han.
O ṣafihan fọnran ohun ti Kanu ti n sọ pe ki wọn maa pa awọn ọlọpaa Naijiria.
Pẹlu eyi to ni oun yoo ṣe ikọlu siluu Eko, ti Tinubu ko si ni i ribi sa si.
Àwọn àṣírí mí-ìn tí ẹlẹ́rìí fi hàn nípa Nnamdi Kanu ree
Ẹlẹrii naa ṣalaye fun kootu, nipa bi Olootu idajọ tẹlẹ ni Naijiria, Abubakar Malami, ṣe kọwe si ọga agba DSS lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa ọdun 2021.
Ninu iwe naa lo ni o ti fi ẹsun igbimọpọ ṣiṣẹ ibi, ipaniyan, didina sun dukia ijọba ati pipa awọn agbofinro leralera kan Kanu.
Ẹlẹrii tẹsiwaju, pe oun gba ọrọ ẹnu Nnamdi Kanu kalẹ lẹyin ti wọn mu un tan.
Kootu gba lẹta olootu idajọ naa wọle gẹgẹ bii ẹri akọkọ.
Wọn gba ohun elo 'flash drive' kan to ka fidio ati fọnran ohun silẹ nipa Nnamdi Kanu, gẹgẹ bii ẹri keji.
Agbefọba Adegboyega Awomolo lo fi eyi fun kootu.
Igbohunsafẹfẹ kan ti Nnamdi Kanu ṣe lọjọ kejila, oṣu Kejila ọdun 2020 lo wa nibẹ.
Ninu fidio naa ni Kanu ti kede pe IPOB ti da ẹgbẹ Eastern Security Network (ESN) silẹ, ninu rẹ lo ti ni: "a ti duro de awọn gomina apa Ila-Oorun Naijiria titi (Southeast) lati ṣe bii awọn ẹgbẹ wọn nilẹẹ Yoruba, ṣugbọn nigba ti wọn ko ti fẹẹ ṣe e, a ti da a silẹ funra wa."
Ohún inu fidio naa ti wọn ni ti Nnamdi Kanu ni, tun n sọ fun ọkan ninu awọn to pe e lori foonu pe ki wọn lọọ wa nnkan ija ti wọn le fi pa awọn ọlọpaa nibikibi ti wọn ba wa.
"Ẹnikẹni tẹ ẹ ba pa, ẹ ge ori rẹ kuro ki wọn le maa lọ si ọrun apaadi." Bẹẹ ni ohun ti wọn ni ti Kanu ni naa wi ninu fọnran yii.
Ninu fidio mi-in, Kanu sọ pe oun yoo fun ẹni to ba le pa Nyesom Wike ni miliọnu lọna ọgọrun-un naira (100m).
O ni aadọta miliọnu (50 million naira) ni Wike loun yoo fun ẹni to ba le gbe ori awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB wa, ṣugbọn oun sọ owo naa di ilọpo meji ni toun, fun ẹni to ba ti ori Wike gbe wa.
Ẹlẹrii BBB sọ fun kootu pe DSS ti ṣafihan fidio ati fọnran ohun yii fun Nnamdi Kan, o si gba pe oun ṣe bẹẹ loootọ.
Àṣírí ń tẹ̀ síwájú

Awọn nnkan mi-in ti wọn tun ni Kanu sọ ninu fidio naa ni
A ko le jẹ ki ẹgbẹ alakatakiti gba ilẹẹ wa rara.
Bi ikọ ọgba ẹranko ba gbiyanju lati pa ọmọ Biafra kan, awa naa yoo gbẹsan pada.
Awọn ojo, ọ̀lẹ atawon ti ko lakaaki la ni nipo gomina.
ESN ta a da silẹ wa fun lati koju awọn ẹhanna to n yọ wa lẹnu lati Sahel.
ESN ki i ṣe ikọ ologun Biafra, ikọ alaabo bii awọn Amọtẹkun ilẹ Yoruba lasan ni.
Ninu fidio mi-in ti wọn tun fi han ni kootu, ohun kan ti DSS ṣo pe ti Nnamdi Kanu ni, n sọ fawọn eeyan pe "ẹ lọọ jo Eko nina raurau", " ẹ dana sun papakọ ofurufu Murtala Mohammed ", "ẹ jó otẹẹli Tinubu yẹn", " ẹ lọ sinu igbo, ẹ gba ibọn lọwọ awọn ọlọpaa kẹ ẹ si pa wọn ".
Ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Fidio miran tun sọ pe "gbogbo ile to ba jẹ ti ijọba apapọ l'Ekoo lo yẹ kẹ ẹ sọna si. "Bi ẹ ba ri mọto ijọba, ẹ ṣọna si i. "Ẹ pese nnkan ija ogun yin funra yin, ẹ dena de wọn."
"Ọlọpaa tẹ ẹ ba ri, ẹ pa wọn, ẹ lọ si teṣan wọn kẹ ẹ kan ina si i, alakatakiti ni wọn ".
Bakan naa ni aṣiri fidio mi-in tun tu nigba ti kootu ṣafihan ibi ti wọn ni Kanu ti sọ pe:
"Tinubu ti wọ wahala, ko le sa lọ. Gbogbo ibi to ba sa de, a maa mu un."
"Bi a ko ba huwa bii were fawọn eeyan ọgba ẹranko yii, ayipada ta a fẹ ko le bọ si i."
"Ẹ maa pa awọn ṣọja bayii, e dena de wọn, ẹ gbẹ iho soju ọna, ki mọto wọn le takiti ki wọn si ku."
Asiko ifẹhonuhan End SARS to waye loṣu Kẹwaa ọdun 2020 lo jọ pe ifọwerọ inu fọnran yii waye, pẹlu bi ohun ti wọn ni ti Kanu ni naa ṣe n dahun ipe awọn to n pe e kaakiri Naijiria.
Wọn n fun un labọ ohun to n ṣẹlẹ nibi ti kalulu wọn duro si i.












